إعدادات العرض
Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ
Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ
Lati ọdọ Sulaiman ọmọ Suradin - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ bayi pe: Mo wa lori ijoko pẹlu Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nigbati awọn arakunrin meji nbu arawọn, ojú ọkan nínú àwọn mejeeji pọ́n kankan, bẹẹni iṣan parikẹ rẹ naa ntana jade, bayi ni Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Re máa ba a) sọ pé: "Dajudaju ẹmi mọ gbólóhùn kan, ti o ba le wi i ni, nkan ti nbi ninu yóò sakuro lọdọ rẹ "ti o ba le sọ pé: "mo wa iṣọ lọdọ Ọlọhun nipa aburu èṣù" (Satani), ibinu ti nbi náà yóò lọ ni wọ́n bá sọ fún un pe: dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a) sọ pe: "yáa wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù" (Satani), Arakunrin náà bá dahun pe: Se weere kọlu mi ni bi?
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tagalog Kurdî Kiswahili Português සිංහල Русский Nederlands Tiếng Việt অসমীয়া ગુજરાતી پښتو Hausa മലയാളം नेपाली ქართული Magyar తెలుగు Македонски Svenska ಕನ್ನಡ Moore Română Українська ไทย मराठी ਪੰਜਾਬੀ دری አማርኛ Wolof ភាសាខ្មែរ Malagasyالشرح
Arakunrin meji njà lọdọ Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a), bẹẹ ni oju ọkan ninu awọn mejeeji ti pọ́n koko, bẹẹ ni isan to yipo ọrun rẹ ti ran jáde. Ni ojisẹ Ọlọhun (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) bá sọ pé: Dajudaju emi mọ gbólóhùn kan ti ẹni to nbinu yii bá wí i, ibinu naa yóò sa kuro fun, ti o ba le sọ pé: mo sa di Ọlọhun nibi aburu èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe. Wọ́n sọ fun un pe: Dajudaju Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) sọ pe: Wá isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani). Ni o ba dahun, o ni: se were ni mi bi?! o le ro pe ẹnikan kò nii wá isọra nipa èṣù (Satani) ayáafi ẹni tí o ba ya were.فوائد الحديث
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) nifẹ ki o máa ṣe itọsọna ati itunise nigbati o ba ti rí okunfa rẹ.
Lati ọdọ èṣù (Satani) ni ibinu ti nwá.
Ipani lasẹ lati wa isọra pẹlu Ọlọhun nipa èṣù (Satani) ẹni ẹkọ ẹni egbe nigbati a ba nbinu, Ọlọhun Allah ti ọla Rẹ ga julọ sọ bayi pe: (Tí ìbínú òdì kan bá sì ṣẹ́rí sínú ọkàn rẹ̀ láti ọ̀dọ̀ èṣù (Satani), fi Allāhu wá ìṣọ́rí ...) dé ìparí aayah.
Isọni lára nibi imaa bu yàn ati nkan mi to tun jọ ọ gẹgẹbí epe ṣiṣẹ, ati ileni kúrò níbi awọn mejeeji, nitori pe a maa mu ibajẹ ṣẹlẹ làárin awọn ènìyàn.
Mímú ọrọ ìmọràn, (ìkìlọ) lọ ba ẹni tí kò tii gbọ ọ; ki o le se anfaani pẹlu nkan to wa nibẹ, ki o si le wúlò fun un.
Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ti sọ wa lara nibi ibinu; nitoripe aa maa tini lọ síbi aburú ati isiwawu, Anọbi (ki ikẹ ati ọla Ọlọhun máa ba a) kii dede binu ayaafi ti wọ́n bá fa ọgbà Ọlọhun ya nìkan, oun náà ni ìbínú ti ó da.
An-Nawawi sọ ọrọ asọle lórí ọrọ rẹ "njẹ moya were ni bi": o le tumọ sí pé ẹni tí o sọrọ jẹ ọkan ninu awọn a seyi sọun (munaafiki), tàbí kí o jẹ ọkan ninu awọn lárúbáwá oko toluko.