“Ẹni tí ó bá gba aawẹ Ramadan ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”

“Ẹni tí ó bá gba aawẹ Ramadan ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Ẹni tí ó bá gba aawẹ Ramadan ni ti igbagbọ ati ireti ẹsan ni ọdọ Ọlọhun, wọn maa fi orí ẹsẹ rẹ ti o ṣáájú jin in”

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe ẹni tí o ba gba aawẹ oṣù Ramadan ni ti igbagbọ ninu Ọlọhun, ati gbigba ìjẹ-ọran-anyan aawẹ ni ododo, ati ohun ti Ọlọhun pèsè kalẹ fun awọn alaawẹ bii ẹsan ti o pọ̀, ni ẹni tí n gbèrò ojú-rere Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ti kii ṣe ti ṣekarimi tabi ṣekagbọmi, wọn maa fi orí àwọn ẹṣẹ rẹ ti o ti kọjá jin in.

فوائد الحديث

Ọlá ti n bẹ fun imọkanga, ati pàtàkì rẹ nibi aawẹ Ramadan, ati awọn iṣẹ rere mìíràn yatọ si i.

التصنيفات

Ọla ti o n bẹ fun awẹ gbigba