Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan

Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan

Lati ọdọ Abu Zubayr, o sọ pe: Ibnu Zubayr jẹ ẹniti o maa n sọ ni ẹyin ìrun kọọkan nigba ti o ba salamọ pe: “Laa ilaaha illa Allāhu wahdahu laa sharīka lahu, lahul mulku wa lahul hamdu wa huwa ala kulli shay’in qodīr, laa haola walā quwwata illā biLlāh, lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu, lahu ni‘matu wa lahul fadlu wa lahuu thanāhul hasan, lā ilāha illā Allāhu mukhlisiina lahuu dīna wa lao karihal kāfirūna”, o wa sọ pe: «Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi wọn ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin gbogbo irun kọọkan».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹniti maa n fi asikiri nla yii ṣe gbólóhùn ìmú-Ọlọ́hun-lọ́kan ni ẹyin ti o ba salamọ ni gbogbo irun ọran-anyan, itumọ rẹ si ni pe: “Lā ilāha illā Allāhu”: Ìyẹn ni pé ko si ẹni ti a maa jọ́sìn fun pẹ̀lú ẹ̀tọ́ ayaafi Allāhu. “Wahdahu lā sharīka lahu” ìyẹn ni pé: Dajudaju ko si akẹgbẹ fun un nibi ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin Rẹ, ati ijẹ Oluwa Rẹ, ati awọn orukọ Rẹ, ati awọn iroyin Rẹ. “Lahul mulku” ìyẹn ni pé: TiRẹ ni ìjọba ti ko ni ààlà ti o kárí, ti o gbòòrò, ìjọba àwọn sánmọ̀ àti ilẹ̀ ati ohun ti n bẹ ni àárín méjèèjì. “Wa lahul hamdu” ìyẹn ni pé: Oun ni Ẹnití a n royin pẹlu pipe ti ko ni ààlà, Ẹni tí a n yin pẹlu pipe ni ti ifẹ ati gbigbe tobi lori gbogbo ìṣesí, nigba idunnu, ati nigba inira. “Wa huwa ‘alā kulli shay’in qodīr”: Ikapa Rẹ pe ni gbogbo ọna, nnkankan o si da A ni agara ri, alamọri kankan o si soro lati ṣe fun Un ninu awọn alamọri. “Lā haola walā quwwata illā biLlāh” ìyẹn ni pé: Ko si iyipada kuro nibi ìṣesí kan sí iṣesi miiran, ati kuro nibi ṣiṣẹ Ọlọhun lọ sí titẹle àṣẹ Rẹ, ko si si agbara kankan ayaafi pẹlu Allāhu, Oun ni Olùrànlọ́wọ́, Oun si ni a maa n gbára lé. “Lā ilāha illā Allāhu, wa lā na‘budu illā iyyāhu”: O jẹ ìkànnípá fun itumọ ìní-ẹ̀tọ́ si ijọsin ati íhánnà ẹbọ (mimu orogun mọ Ọlọhun), ati pe ko si ẹnití o lẹtọọ si ijọsin ayaafi Oun. “Lahu ni‘motu wa lahul fadlu”: Oun ni O n ṣẹda awọn idẹkun ti O ni ikapa rẹ, ti O si maa n fi i da ọla lori ẹnití o ba wu U ninu awọn ẹru Rẹ. “Wa lahu thanāhul hasan”: Lórí pàápàá Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ ati awọn idẹra Rẹ, ati lori gbogbo ìṣesí. “Lā ilāha illā Allāhu, mukhlisiina lahu dīna”: Ìyẹn ni pe ni ẹni ti wọn a maa mu Un ni Ọkan ṣoṣo laisi ṣekarini ati ṣekagbọni nibi titẹle Ọlọhun. “Wa lao karihal kāfirūna”, ìyẹn ni pe: Ni ẹni tí wọn fi ẹsẹ rinlẹ lori mimu Ọlọhun ni Ọkan ṣoṣo ati jijọsin fun Un, koda ki awọn alaigbagbọ korira rẹ.

فوائد الحديث

A fẹ́ ki a maa dunni mọ iranti yii lẹyin gbogbo irun ọranyan kọọkan.

Musulumi a maa ṣe iyanran pẹlu ẹsin rẹ yio si tun maa fi awọn arisami rẹ han koda ki awọn alaigbagbọ korira rẹ.

Ti gbolohun: “Duburu Sọlaat” ba wa nínú hadiisi, ti nkan ti o wa ninu hadīth yẹn ba jẹ àsíkìrí, ipilẹ rẹ ni ki o jẹ ẹyin salamọ, ti o ba wa jẹ adua, iwaju salamọ ni yio jẹ.

التصنيفات

Awọn iranti irun