Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún

Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún

Láti ọ̀dọ̀ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún, o lo ọdún mẹtala ni ìlú Makkah, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ ki o ṣe hijra, o wa ṣe hijra lọ sí ìlú Madina, o wa lo ọdún mẹ́wàá nibẹ, lẹyin naa ni o wa kú (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n sọ pe: Wọn sọ ìmísí kalẹ fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wọn si gbé e dìde nígbà tí o pe ọmọ ogójì ọdún, o wa ni ilu Makkah fun ọdún mẹtala lẹ́yìn ìmísí, lẹyin naa ni wọn pa a láṣẹ lati ṣe hijra lọ sí ìlú Madina, o wa wa nibẹ fun ọdún mẹ́wàá, lẹyin naa ni o wa kú ni ọmọ ọdún mẹtalelọgọta.

فوائد الحديث

Akolekan àwọn saabe si itan ìgbésí ayé Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a).

التصنيفات

Anọbi wa Muhammad- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, Itan ti Anabi