إعدادات العرض
Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin
Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin
Lati ọdọ 'Irbaad ọmọ Saariyah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- duro laaarin wa ni ọjọ kan, o wa ṣe waasu kan ti o de ògòńgó fun wa ti awọn ọkan ń gbọn riri latara rẹ, ti awọn oju n dami latara rẹ, wọn wa sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, o ṣe waasu idagbere fun wa, sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun wa. O sọ pe: "Ibẹru Ọlọhun dọwọ yín, ati gbigbọ ati itẹle, ko da ki o jẹ ẹru dúdú, ẹ maa pada ri iyapa ẹnu ti o le koko lẹyin mi, sunnah mi ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a ti fi wọn mọna dọwọ yin, ẹ di wọn mu pẹlu eyin ọgan, ẹ ṣọra fún awọn adadaalẹ, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni".
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or नेपाली Malagasy Română Kinyarwanda বাংলা తెలుగు Bosanski Kurdî Lietuvių Oromoo മലയാളം Nederlands Soomaali Shqip Српски Deutsch Українська ಕನ್ನಡ Wolof Moore Português ქართული Azərbaycan 中文 Magyar فارسی Tagalog தமிழ் Македонскиالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe waasu kan ti o de ogongo fun awọn saabe, ti awọn ọkan gbọn ti awọn oju dami latara rẹ, Wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun o da gẹgẹ bii waasu idagbere fun nnkan ti wọn ri ninu wiwọnu rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi waasu náà, wọn wa beere fun àsọtẹ́lẹ̀ ki wọn le gba a mu lẹyin rẹ, O sọ pe: Mo n sọ àsọtẹ́lẹ̀ fun yin pẹlu ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-, ìyẹn maa rí bẹ́ẹ̀ pẹlu ṣíṣe awọn nnkan ti wọn jẹ dandan ati gbigbe awọn eewọ ju silẹ, Ati gbigbọ ati itẹle, o n túmọ̀ si: Fun awọn adari, ko da ki ẹru jẹ adari fun yin, o n túmọ̀ si ki ẹni ti o kere julọ ninu ẹda di adari le yin lori, ẹ ko gbọdọ kọ ìyẹn, ki ẹ si tẹle e, ni ti ipaya dídá fitina sílẹ̀, dajudaju ẹni ti o ba ṣẹmi ninu yin maa pada ri iyapa ti o pọ, Lẹyin naa o ṣàlàyé ọna àbáyọ fun wọn kuro nibi iyapa yìí, ìyẹn pẹlu gbigba sunnah rẹ mu ati sunnah awọn arole ẹni imọna ti a fi ọna mọ wọn lẹyin rẹ, Abu Bakr, ati Umar ọmọ Khattaab, ati Uthman ọmọ 'Affan, ati Aliy ọmọ Abu Toolib- ki Ọlọhun yọnu si wọn lapapọ-, ati gbigba a mu pẹlu ẹyin ọgan, o n túmọ̀ si- awọn ẹyin ẹgbẹ ti o kẹ́yìn-: O n túmọ̀ ẹyin ọgan yẹn si didunnimọ sunnah daada ati didirọmọ ọn, O ṣe ikilọ fun wọn kuro nibi awọn alamọri ti a da wọn silẹ sinu ẹsin, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni.فوائد الحديث
Pataki didirọmọ sunnah ati itẹle ẹ.
Akolekan si awọn waasu ati rirọ awọn ọkan.
Pipaṣẹ pẹlu itẹle awọn arole ẹni imọna ti a fi wọn mọna mẹrẹẹrin lẹyin rẹ, awọn ni Abu Bakr, ati Umar, ati Uthman, ati Aliy- ki Ọlọhun yọnu si wọn-.
Kikọ kuro nibi adadaalẹ ninu ẹsin, ati pe dajudaju gbogbo adadaalẹ anu ni.
Gbigbọ ati itẹle fun ẹni ti o ba n dari alamọri awọn olugbagbọ ni ọna ti o yàtọ̀ si oju ọna ẹṣẹ.
Pataki ibẹru Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- ni gbogbo asiko ati iṣesi.
Iyapa jẹ nnkan ti o n ṣẹlẹ̀ ninu ijọ yìí, nigba ti o ba ṣẹlẹ̀, ṣiṣẹripada si sunnah ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ati ti awọn arole ẹni imọna maa jẹ dandan.