Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi…

Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}

Lati ọdọ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i-: Pe Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni gbogbo alẹ́, o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, lẹyin naa o maa fẹnu fẹ atẹ́gùn túẹ́túẹ́ sinu méjèèjì, o maa wa ka sínú méjèèjì: {Qul Uwal Loohu Ahad}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq}, ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹyin naa o maa fi méjèèjì pa ibi ti o ba ṣeé pa ni ara rẹ, o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ ati oju rẹ, ati ẹ̀yà ti iwájú ninu ara rẹ, o maa ṣe bẹ́ẹ̀ ni ẹẹmẹta.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Nínú ìtọ́sọ́nà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ba ti fẹ sùn ni pe o maa pa atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pọ̀, o si maa gbe wọn sókè- gẹgẹ bi ẹni tí n ṣe adua- o maa wa rọra fẹnu fẹ́ atẹ́gùn si i pẹ̀lú itọ́ díẹ̀, o maa ka àwọn suura mẹtẹẹta naa: {Qul Uwal Loohu Ahad} ati {Qul Ahuuzu bi Robbil falaq} ati {Qul Ahuuzu bi Robbin naas}, lẹ́yìn náà ni o maa fi atẹlẹwọ rẹ méjèèjì pa ibi ti o ba ṣee pa ni ara rẹ; o maa bẹ̀rẹ̀ lati orí rẹ, ati ojú rẹ, ati ẹya iwaju ara rẹ, o maa pààrà rẹ ni ẹẹmẹta.

فوائد الحديث

Fifẹ kika suuratul Ikhlaas ati Qul Ahuuzu kìíní-kejì ṣiwaju oorun, ati fifi wọn fẹnu fẹ atẹgun túẹ́túẹ́, ati fifi wọn pa ohun ti o ba ṣee pa ninu ara rẹ.

التصنيفات

Ọla ti n bẹ fun àwọn suura ati awọn aaya, Ọla ti n bẹ fun àwọn suura ati awọn aaya, Awọn ẹkọ orun sisun ati jiji, Awọn ẹkọ orun sisun ati jiji