إعدادات العرض
«Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika
«Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika
Lati ọdọ Abu Sa’ēd Al-Khuduriy o sọ pe: Mu’āwiya lọ sibi àpéjọ kan ninu masalasi, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo fun iranti Ọlọhun, o sọ pe: Ẹ bura pẹlu Ọlọhun pe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn? Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe: Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ko si si ẹnikankan ti o wa ni iru ipo mi si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti ẹgbawa hadiisi rẹ lati ọdọ rẹ (Anabi) kere to temi: Ati pe dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade si ibi akojọ awọn saabe rẹ, ni o wa sọ pe: Kini nkan ti o mu yin jokoo? Wọn sọ pe: A jokoo lati maa ranti Ọlọhun ati lati maa fi ẹyin fun Un lori bi O ṣe fi wa m'ọna si Isilaamu, ati idẹkun ti O fi i ṣe le wa lori, o sọ pe: «Ẹ bura pẹlu Ọlọhun ṣe nkankan o mu yin jokoo ayaafi ìyẹn?» Wọn sọ pe: A fi Ọlọhun bura ko si nkankan ti o mu wa jokoo ayaafi ìyẹn, o sọ pe : «Mi o ni ki ẹ bura nítorí pé mo n fẹsun kan yin o, ṣugbọn Jubril wa ba mi o si fun mi ni iro pe dajudaju Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n ṣe iyanran pẹlu yin ni ọdọ awọn malaika».
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Hausa Kurdî മലയാളം Kiswahili Português සිංහල دری Svenska አማርኛ অসমীয়া ไทย Tiếng Việt Кыргызча ગુજરાતી Malagasy नेपाली Oromoo Română Nederlands Soomaali پښتو తెలుగు Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Српски Mooreالشرح
Mu‘āwiyah ọmọ Abu Sufyaan- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- jade sibi akojọ kan ninu masalasi, ni o wa bi wọn pe kini nkan ti wọn tori rẹ kojọ, Wọn wa sọ pe: A n ranti Ọlọhun ni, Ni o wa sọ - ki Ọlọhun yọnu si i - pe ki wọn o fi Ọlọhun bura pe wọn o gbero nkankan nibi ijokoo wọn ati akojọpọ wọn yẹn ayaafi iranti Ọlọhun, Wọn si bura fun un, Lẹyin naa ni o wa sọ fun wọn pe: Dajudaju kii ṣe pe mo ni ki ẹ bura láti fi ẹsun kan yin ati lati ṣe iyemeji nipa ododo yin, lẹyin naa ni o sọ nipa ipo rẹ si Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pe ko si ẹnikankan ti ipo rẹ sunmọ ọn - Anabi - to oun; latari pe Umu Habiibah ọmọ ìyá rẹ obinrin jẹ iyawo Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, ati pe o tun wa ninu awọn ti wọn maa n kọ waayi (imisi), tòun ti bẹ́ẹ̀ náà ẹgbawa rẹ fun hadiisi kere, Ni o wa sọ fun wọn pe dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jade lati inu ile rẹ ni ọjọ kan, ni o wa ri wọn ti wọn jokoo ninu masalasi ti wọn n ṣe iranti Ọlọhun ti wọn si n yin In lori ọna Isilaamu ti O fi mọ wọn, ti O si fi ṣe idẹkun le wọn lori, ni o wa bi wọn leere - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ti o si tun ni ki wọn o bura bi iru nkan ti Mu‘āwiya - ki Ọlọhun yọnu si i - ṣe pẹlu awọn eeyan rẹ, Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ fun wọn idi ibeere rẹ fun ibura wọn: Oun ni pe Jubril - ki ọla Ọlọhun maa ba a - wa ba oun ti o si fun oun ni iro pe Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn n fi yin ṣe iyanran niwaju awọn malaika, ti O si n ṣe afihan ọla yin fun wọn, ti O si tun n fi didaa iṣẹ yin han wọn, ti O si tun n yin yin loju wọn.فوائد الحديث
Ọla Mu‘āwiya - ki Ọlọhun yọnu si i - ati ojukokoro rẹ lori kikọṣe ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nibi mímú imọ de etiigbọ awọn eeyan.
Jijẹ ẹtọ bibeere fun ibura lai si ifura si, lati ṣe itaniji lórí pataki ìròyìn naa.
Ọla ti n bẹ fun awọn ijokoo iranti ati imọ ati pe dajudaju Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si i O si tun maa n ṣe iyanran pẹlu rẹ niwaju awọn malaika.