Dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba n kirun yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji titi ti abiya rẹ mejeeji o fi han

Dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba n kirun yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji titi ti abiya rẹ mejeeji o fi han

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Mālik ọmọ Buhayna - ki Ọlọhun yọnu si i -: Dajudaju Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba n kirun yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji titi ti abiya rẹ mejeeji o fi han.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fi ori kanlẹ yio fi alafo si aarin ọwọ rẹ mejeeji ni iforikanlẹ; yoo si gbe ọwọ kọọkan jina si ibi ẹgbẹ ti o wa, gẹgẹ bii iyẹ meji, titi ti awọ abiya rẹ fi maa han; Ati pe eyi n bẹ ninu jijẹ ki apá méjèèjì da bii iyẹ ati gbigbe wọn jìnà gan si ẹgbẹ rẹ mejeeji.

فوائد الحديث

Ṣiṣe iṣesi yii ni ẹtọ nibi iforikanlẹ, oun naa ni gbigbe apa mejeeji jina si ẹgbẹ rẹ mejeeji.

Olukirun lẹyin imaamu ti o ṣe wipe ara o maa ni ẹni ti o wa ni ẹgbẹ rẹ latara gbigbe ọwọ jina si ara wọn; ko tọ fun un ki o ṣe e.

O n bẹ nibi igbe ọwọ jina si ara wọn nibi iforikanlẹ awọn ọgbọn ati anfaani ti o pọ, ninu rẹ ni: Fifi ijafafa ati ini ìfẹ́ si irun han, ti o ba da ara le gbogbo oríkèé iforikanlẹ, gbogbo oríkèé kọọkan ni yio gba ẹtọ rẹ nibi ijọsin. Wọn tun sọ pe: Ọgbọn ti o wa nibi iyẹn ni pe o jọ itẹriba, o si de ogongo nibi fifi iwaju ati imu le ilẹ daadaa, ati pe bákannáà ki oríkèé kọọkan le da yatọ.

التصنيفات

Ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi irun