Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in

Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in

Lati ọdọ Humraan ẹru Uthman ọmọ ‘Affan pé o ri Uthman ọmọ ‘Affan ti o beere fun omi aluwala, o ti ọwọ rẹ mejeeji bọ inu igba rẹ, o fọ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ ọtun bọ inu omi aluwala, lẹyin naa o fi omi yọ ẹnu rẹ o si fin in simu o si fin in síta, lẹyin naa o fọ oju rẹ lẹẹmẹta, ati ọwọ rẹ mejeeji titi de igunpa rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o pa ori rẹ, lẹyin naa o fọ gbogbo ẹsẹ rẹ lẹẹmẹta, lẹyin naa o sọ pe: Mo ri Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o n ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yìí, o wa sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bi mo ṣe ṣe aluwala mi yii lẹyin naa o wa ki rakah meji ti ko ba ẹmi rẹ sọrọ nibi mejeeji, Ọlọhun yoo fori nnkan ti o ṣíwájú ninu ẹṣẹ rẹ jin in”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- kọ wa ni bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe maa n ṣe aluwala pẹlu oju ọna fifi ṣe iṣẹ ṣe; ki o le baa kun ni alaye, lẹyin naa o beere fun omi ninu igba, o wa da a si ọwọ rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o ti ọwọ rẹ ọtun bọ inu igba, o fi bu omi o si da a si ẹnu rẹ o si mu u jáde, lẹyin naa o fin omi fun ara rẹ sinu imu rẹ, lẹyin naa o mu u sita o si fin in síta, lẹyin naa o fọ oju rẹ lẹẹmẹta, lẹyin naa o fọ ọwọ rẹ mejeeji pẹlu igunpa rẹ mejeeji lẹẹmẹta, lẹyin naa o mu ọwọ rẹ re kọja lori ori rẹ ni nnkan ti o tutu fun omi lẹẹkan, lẹyin naa o fọ ẹsẹ rẹ mejeeji pẹlu kokosẹ rẹ mejeeji lẹẹmẹta. Nigba ti Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- pari o sọ fun wọn pe dajudaju oun ri Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o ṣe aluwala gẹgẹ bii aluwala yii, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa fun wọn ni iro idunnu pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala gẹgẹ bii aluwala rẹ, ti o wa ki rakah meji, ni ẹni ti o n wa ni irẹlẹ ti ọkan rẹ si wa lori irun niwaju Oluwa rẹ- Alagbara ti O gbọnngbọn- nibi mejeeji, dajudaju Ọlọhun yoo san an lẹsan lori aluwala ti o pe yii ati irun ti o mọ kanga yii pẹlu aforijin nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ rẹ.

فوائد الحديث

Ṣiṣe fifọ ọwọ mejeeji ni nnkan ti a fẹ ṣíwájú titi mejeeji bọ inu igba ni ibẹrẹ aluwala, ti o ba ṣe pe ko dide lati ojú orun, ṣùgbọ́n ti o ba ṣe pe o ji lati oju orun oru, fifọ mejeeji jẹ dandan.

O tọ fun olukọ lati tọ oju ọna ti o sunmọ julọ sibi agbọye ati irinlẹ imọ lọdọ oluwa imọ, ninu ìyẹn ni kikọ awọn eniyan lẹkọọ pẹlu iṣe.

O tọ fun olukirun lati ti awọn ero ti wọn so pọ mọ awọn airoju aye dànù, ati pe pipe irun n bẹ nibi ki ẹmi wa nibẹ, ti ko ba ri bẹ́ẹ̀, àtilà nibi awọn ero maa n ṣoro, o wa jẹ dandan fun un lati ja ẹmi rẹ logun ki o si ma túra silẹ nibi ìyẹn.

Ṣíṣe bibẹrẹ pẹlu apa ọtun ni nnkan ti a fẹ nibi aluwala.

Ṣíṣe titotẹlera laaarin fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi simu ati fifin in sita lofin.

Ṣíṣe fifọ oju ati ọwọ mejeeji ati ẹsẹ mejeeji lẹẹmẹta ni nnkan ti a fẹ, ati pe eyi ti o jẹ dandan ni fifọ wọn lẹẹkan.

Aforijin Ọlọhun fun nnkan ti o ṣíwájú ninu awọn ẹṣẹ wa lori akojọpọ alamọri méjì: Aluwala, ati kiki rakah méjì, lori iroyin ti wọn darukọ ninu Hadiisi.

Aala n bẹ fun gbogbo orikee ara kọọkan ninu awọn orikee aluwala: Aala oju ni: Lati ibi ti irun ori ti bẹ̀rẹ̀, titi de ibi ti o wálẹ̀ ninu irungbọn ati agbọn ni òró, ati lati eti kan si keji ni ibu. Aala ọwọ ni: Lati awọn eteeti awọn ọmọnika titi de igunpa, oun ni ibi asopọ laaarin ọwọ ati apa. Aala ori ni: Lati ibi ti irun ti maa n saaba hù nibi ẹgbẹ oju si oke ọrun, ati pe pipa eti mejeeji wa lara ori. Aala ẹsẹ ni: Gbogbo ẹsẹ pata pẹlu ibi asopọ ti o wa laaarin rẹ ati laaarin ojugun.

التصنيفات

Iroyin aluwala