Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ

Lati ọdọ Aaisha Iya awọn Mumuni - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba ti fẹ wẹ janaba, yio fọ ọwọ rẹ mejeeji, yio si tun ṣe aluwala rẹ ti maa n ṣe fun irun, lẹyin naa yio wẹ, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun rẹ, titi ti yio fi ro ni ẹmi rẹ pe o ti kan awọ isalẹ irun rẹ, yio wa da omi si ara ni ẹẹmẹta, lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku, ni o wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ papọ ninu igba kan náà, ti a si jọ maa n fi ọwọ bu omi papọ ninu rẹ.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - jẹ ẹni ti o ṣe pe ti o ba fẹ wẹ janaba yio bẹrẹ pẹlu fifọ ọwọ rẹ mejeeji, Lẹyin naa ni yio wa ṣe aluwala gẹgẹ bi o ṣe maa n ṣe aluwala fun irun, lẹyin naa yio fi ọwọ rẹ mejeeji ya irun ori rẹ, titi ti yio fi ni lọkan pe omi ti de isalẹ irun, ti o si ti jẹ ki awọ ori mumi yo, yio waa da omi si ori ni ẹẹmẹta lẹyin naa yio wẹ ara rẹ yoku. Aaisha - ki Ọlọhun yọnu si i - wa sọ pe: Mo jẹ ẹni ti emi pẹlu ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - maa n wẹ ninu igba kan náà ti a o jọ maa fi ọwọ bu omi ninu rẹ papọ.

فوائد الحديث

Iwẹ iran meji ni: Eyiti o toni ati eyiti o pe, ẹẹ wa ri iwẹ ti o toni, ọmọnìyàn o da aniyan imọra, lẹyin naa yio fi omi kari gbogbo ara rẹ pẹlu fifi omi yọ ẹnu ati fifin omi si imu, ṣugbọn iwẹ ti o pe, yio wẹ gẹgẹ bi Anabi ṣe wẹ ninu hadīth yii.

Wọn maa n lo Janaba fun gbogbo ẹni ti o ba da atọ si ara, tabi ti o ba ni ibalopọ koda ki o ma da atọ.

Jijẹ ẹtọ ki ọkọ ati iyawo o maa wo ihoho ara wọn, ati ki wọn maa wẹ papọ ninu igba kan naa.

التصنيفات

Iwẹ