Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun

Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: "Ko si àkóràn, tabi fifi ẹyẹ fura mọ aburu, tabi fifi ẹyẹ owiwi fura mọ ìṣẹ̀lẹ̀ àjálù, tabi fifi oṣu Safar fura mọ aburu, ki o si sa fun adẹtẹ gẹgẹ bi o ṣe maa n sa fun kinihun".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé awọn kan ninu awọn àlámọ̀rí asiko aimọkan ni ti siṣekilọ kuro nibẹ, ati ṣíṣe àlàyé pe dajudaju àlámọ̀rí ọwọ Ọlọhun ni o wa, ati pe nnkan kan ko le ṣẹlẹ̀ afi pẹlu àṣẹ Rẹ ati kadara Rẹ, awọn ni: Akọkọ: Awọn ara asiko aimọkan n lero pe dajudaju aisan maa n ran fun ara rẹ; ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi kọ kuro nibi adisọkan ṣíṣí aisan latara alaisan sọ́dọ̀ ẹlòmíràn fúnra rẹ; Ọlọhun ni n ṣàkóso ayé; Oun ni O n sọ aisan kalẹ ti O si n gbe e kuro, ìyẹn ko lee ṣẹlẹ̀ afi pẹlu fifẹ Rẹ ati kadara Rẹ. Ikeji ni: Awọn ara asiko aimọkan ti wọn ba jade fun ìrìn-àjò tabi òwò, wọn maa lé ẹyẹ lọ, ti o ba fo si agbegbe ọtun wọn maa dunnu, ti o ba fo si agbegbe osi wọn maa fura mọ aburu wọn si maa ṣẹri pada, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ kuro nibi ifura mọ aburu yii pẹlu ẹyẹ, ti o si ṣàlàyé pe adisọkan ibajẹ ni. Ikẹta: Awọn ara asiko aimọkan maa n sọ pe: Ti ẹyẹ owiwi bá bà lori ile kan, àjálù kan maa ṣẹlẹ̀ si awọn ara ile náà; ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe kọ kuro nibi ifura mọ aburu pẹlu ìyẹn. Ikẹrin: O kọ kuro nibi ifura mọ aburu pẹlu oṣu safar, oun ni oṣu keji ninu awọn oṣu ti òṣùpá. Wọ́n tún sọ pé 'Safar' jẹ́ ejò tó ń gbé inú ikùn, tó ń ṣàkóbá fún ẹran ọ̀sìn àti ènìyàn. Wọ́n sọ pé ó máa ń ranni ju àrùn ìgbóná lọ; ni o wa tako adisọkan yii. Ikarun-un: Ó pàṣẹ pé kí wọ́n yẹra fún ẹni tí àrùn ẹ̀tẹ̀ bá n bẹ lára rẹ gẹ́gẹ́ bí ìwọ yóò ṣe yẹra fún kìnnìún, gẹ́gẹ́ bí ìṣọ́ra fún ara rẹ, ati wiwa ààbò fun un, àti ṣíṣe àwọn ìdí tí Ọlọhun pa láṣẹ. Ẹ̀tẹ̀ jẹ́: Àìsàn tó máa ń ba àwọn ẹ̀yà ara jẹ́.

فوائد الحديث

Ijẹ-dandan igbarale Ọlọhun ati fifi ara ti I, ati ṣíṣe awọn okunfa ti a ṣe lofin.

Jijẹ dandan ini igbagbọ ninu idajọ Ọlọhun ati kadara Rẹ, ati pe dajudaju awọn okunfa wa lọwọ Ọlọhun, Oun ni O maa n mu wọn ṣẹlẹ̀ ti O si maa n ka ilapa wọn kuro.

Biba nnkan ti awọn kan ninu awọn eniyan maa n ṣe jẹ bii èrò òdì nípa àwọ̀, bíi àwọ̀ dúdú àti àwọ̀ pupa, tàbí nípa àwọn nọ́ńbà kan, orúkọ, àwọn èèyàn àtàwọn aláàbọ̀ ara.

Nibi idinamọ isunmọ adẹtẹ ati iru rẹ ninu awọn ti wọn ni awọn aisan ti wọn maa n ran; ó wà lára àwọn ìdí tí Ọlọ́run maa n jẹ ki o sáábà maa n fa irú àrùn bẹ́ẹ̀; ati pe awọn okunfa ko lee da duro fun ara rẹ, bi ko ṣe pe Ọlọhun ni Ẹni ti o ṣe pe ti O ba fẹ O maa gba agbára lọ́wọ́ rẹ̀ ti ko si nii lapa kankan, ti O ba si fẹ O maa ṣẹ ẹ ku ki o lapa.

التصنيفات

Awọn ibeere asiko aimọkan, Awọn iṣẹ ọkan