È sun mọnra, ẹ se daada, ki ẹ lọ mọ pe kò sí ẹnikan ninu yin ti yoo la pọlu iṣẹ ọwọ rẹ" awọn ọmọlẹyìn rẹ sọ bayii pe: Se ati iwọ naa irẹ ojisẹ Ọlọhun? Anọbi daun oni: ati emi naa, ayaafi ki Ọlọhun da gaga ikẹ Rẹ ati aanu Rẹ lemi lori (ki…

È sun mọnra, ẹ se daada, ki ẹ lọ mọ pe kò sí ẹnikan ninu yin ti yoo la pọlu iṣẹ ọwọ rẹ" awọn ọmọlẹyìn rẹ sọ bayii pe: Se ati iwọ naa irẹ ojisẹ Ọlọhun? Anọbi daun oni: ati emi naa, ayaafi ki Ọlọhun da gaga ikẹ Rẹ ati aanu Rẹ lemi lori (ki Ọlọhun siji àánu Rẹ bò mi)

Lati ọdọ Abu Hurayrah - kí Ọlọhun bá wa yọnu si i, o sọ bayi pe: Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a - sọ bayi pe: "È sun mọnra, ẹ se daada, ki ẹ lọ mọ pe kò sí ẹnikan ninu yin ti yoo la pọlu iṣẹ ọwọ rẹ" awọn ọmọlẹyìn rẹ sọ bayii pe: Se ati iwọ naa irẹ ojisẹ Ọlọhun? Anọbi daun oni: ati emi naa, ayaafi ki Ọlọhun da gaga ikẹ Rẹ ati aanu Rẹ lemi lori (ki Ọlọhun siji àánu Rẹ bò mi) .

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi (ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a) ṣe awọn ọmọlẹyìn loju kòkòrò (o fa ifẹ wọn) síbi imaa sisẹ, ati ki wọn si bẹrù Ọlọhun bi wọn ba se ni agbara mọ, láì ṣe àṣe kọja ààlà, ati láì ṣe asee to, ki wọn ni eero iṣẹ àṣe dara pẹlu imáa ṣe iṣẹ wọn nítorí ti Ọlọhun (aniyan tori Ọlọhun) ati imáa tẹlé ilana ati alaalẹ anọbi, ki iṣẹ wọn le jẹ àtéwọgbà, atipe ki o jẹ okunfa isọkalẹ àánu Ọlọhun fún wọn. O si tun fún wọn niro pe isẹ enikọọkan yin nikan ko lee gbayinla, sugbọn afi ki ẹ rí ikẹ gba lọdọ Ọlọhun. Wọn sọ pe: titi o fi de orí rẹ, irẹ ojisẹ Ọlọhun, iṣẹ rẹ ko lee gbaọla toun ti bi o se tobi to? Anọbi sọ pe: titi ofi dé orí mi, ayaafi ki Ọlọhun bomi lasiri pẹlu aanu Rẹ.

فوائد الحديث

An-nawawi sọ bayi pe: (Ẹ se deede, ẹ jẹ kí isunmọ wa): ẹ wa ọna iṣe dọgba, ki ẹ si ṣe àmúlò rẹ, ti ẹ bá wa kagara lati se e, ẹ yáa sun mọn ọn iṣe dọgba dọgba, eyi túmò sí pé: ẹ sun mọn iṣẹ,

itumo iṣe deede ni pe ki a ṣe ohun ti o lẹtọ, ohun náà ni o wa laarin aseeto ati àṣe kọja ààlà, nitori naa ẹ ma se aseeto bẹẹ ni ki ẹ ma se asekọja ààlà.

Ibn Baz sọ pe: awọn iṣẹẹre ohun ni awọn okunfa wiwọ ọgbà idẹra, bo se jasipe isẹẹbi (iṣẹ aburu ti ko da) ohun ni òkùnfà wíwọ ina, Hadith náà nsalaye pe dájúdájú wíwọ ọgbà idẹra kii se pẹlu isẹ lasan (kikida isẹ lasan) sugbọn aní lati ri amojukuro ati ikẹ Ọlọhun mimọ ati gíga ni Fún Un, wọn wọ ọgba Idẹra pẹlu okunfa isẹ wọn, sugbọn eyiti o jẹki o ribẹ ni ikẹ Rẹ - mimọ ni Fún Un - ati amojukuro ati aforinjin Rẹ.

Ẹrusin (ọmọniyan) ko gbọdọ gba itanjẹ pẹlu isẹ rẹ, tabi jọra rẹ loju botiwu ki iṣẹ náà pọ to; nitoripe ẹtọ (iwọ) Ọlọhun tobi ju iṣẹ rẹ lọ, ẹrusin (ọmọniyan) ni lati ni ifoya ati inireti papọ.

Aanu Ọlọhun ati ikẹ rẹ fún àwọn ẹrùsin (ọmọniyan) Rẹ gbaa ye (o sI fẹ) ju iṣẹ wọn lọ.

Awọn iṣẹẹre ni okunfa wíwọ alujanna, bẹẹni jijere rẹ a máà waye pẹlu àánu ati ikẹ lati ọdọ Ọlọhun.

Al-kirmaani sọ pe: "ti o ba se pe gbogbo eniyan ko le wọ ọgba-idẹra (alujanna) ayaafi pẹlu ikẹ Ọlọhun ati aanu Rẹ, ona ti Òjíṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - gba se adayanri rẹ fún idarukọ ara rẹ ni pe ti o ba ti daju fun-un pe yóò wọ ọgba-idẹra, ti o si jẹ pe ko nii wọ ọ ayaafi pẹlu aanu Ọlọhun, nitori naa ẹni ti o ba yatọ si Anọbi nibi eleyun ni o lẹtọ si aanu Ọlọhun julọ.

An-nawawi so bayi pe: nipa itumo ọrọ Ọlọhun ti o ga julo: (Éwo inu ile-idera latara okunfa nkan ti e nse nise).

(An-Nahl: 32),

(Eleyun ni ọgbà idera eyi ti a jogun rẹ fún yín láti ara okunfa nkan ti e nṣe nise). (Zuhkruf: 72), ati awon aayah miran ti ntọka sí pe ise daada aama ṣe okunfa wíwọ ọgbà idera, awọn itumo ọrọ yi ko ni àtakò sí awon Hadith wonyi, sugbon itumo awon aayah yi ni pe awon iṣẹ daada aama ṣe okunfa wíwọ ilè ìdèra, leyinna ni ifini se konge ṣiṣe iṣẹ náà, ati ifinimona sí bí sisé iṣẹ náà nítorí èrò tí Olohun, ati itewogba níwájú Olohun pẹlu aanu ati ike Rẹ, Oba ti o ga jù lọ, ni gbogbo re fi waye, yóò wá jasipe kii se iṣẹ nikan ni o fi wo ile-idera, eleyi ni nkan ti awon Hadith náà tumon sí. O leto ki a sope o wọ ile-idera pelu ise, eyi nipe pẹlu okunfa, ti o se pe ninu aanu ni.

Ibnul-Jaoziy so pe: idahun ( ifesi fin ni) merin otooto ni o je yọ latara ọrọ naa;

Alakoko: Dajudaju ifinise konge iṣẹ ninu ikẹ Olohun ni, ti kii baa se ikẹ Olohun ti o ti gbawaju, ini igbagbo ati itẹle aṣẹ Olohun eyi ti akoyo fi lè wáyé.

Elekeji: Ohun ni pe iwulo eru ti olowoori rẹ nise, iṣẹ rẹ eto ni o je fún oga re, botiwu ki o se idẹra esan fún to, ara àánu oga re ni o jẹ.

Eketa: Oti wa ninu awon Hadith kan pe wíwọ ọgbà idẹra pẹlu ike Olohun ni, sugbon pinpin awon ipo inu re ni yóò máa waye pelu ise oni kaluku.

Ekerin: dajudaju awon iṣẹ itẹle aṣẹ Olohun a máà waye larin asiko diẹ (niwanba), bẹẹni esan re kii tan, iṣẹ idẹra tabi igbadun ti kii tan lati se esan fún iṣẹ ti o ti pari aanu ni o je kii se esan ti o se deede awon ise ti wan se.

Ar-Rafih so pe: dajudaju ko ye ki osise gbára lé iṣẹ rẹ tí o fí nwa akoyo ati ipo, nitoripe iṣẹ pelu konge

(deede) Olohun ni, nitoripe o pa ese ti pẹlu isọ

(ààbò) Olohun ni, gbogbo nkan wonyi waye pẹlu aanu Olohun ati ike Rẹ ni.

التصنيفات

Taohiid ti àwọn orúkọ ati awọn iroyin