إعدادات العرض
Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa…
Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”
Lati ọdọ Ibnu Abbaas (ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji) Lati ọdọ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu nǹkan ti o gba wa lati ọdọ Oluwa rẹ ti O lágbára ti O gbọnngbọn, o sọ pé: “Dájúdájú Ọlọhun kọ daadaa ati aburu, lẹyin naa O ṣalaye ìyẹn, ẹni tí ó bá gbèrò dáadáa, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pé, ti o ba wa gbero rẹ, ti o wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa mẹ́wàá titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ̀, ẹni ti o ba gbèrò aburu, ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni ọdọ Rẹ ni dáadáa ti o pe, ti o ba wa gbero rẹ ti o si ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan”.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Bahasa Indonesia Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी Français Tiếng Việt Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் မြန်မာ Русский Deutsch 日本語 پښتو অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands ئۇيغۇرچە සිංහල ไทย دری Fulfulde Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių or Română Kinyarwanda Српски тоҷикӣ O‘zbek Moore नेपाली Oromoo Wolof Soomaali Български Українська Azərbaycan bm ქართული Македонски Malagasyالشرح
Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n ṣàlàyé pe Ọlọhun ti kádàrá dáadáa ati aburú, lẹyin naa O ṣàlàyé fun awọn malaika méjèèjì bi wọn ṣe maa kọ ọ: Ẹni tí ó bá gbèrò ṣíṣe dáadáa, wọn maa kọ ọ fun un ni dáadáa ẹyọkan koda ki o ma ṣe e, ti o ba wa ṣe e, wọn maa ṣe adipele rẹ pẹlu ìlọ́po mẹ́wàá irú rẹ titi de ìlọ́po ẹẹdẹgbẹrin, titi de ìlọ́po ti o pọ, alekun naa maa wa ni ibamu si bi ọkàn ba ṣe ni imọkanga sí, ati bi àwọn èèyàn ba ṣe ṣe anfaani latara rẹ̀ si, ati ohun ti o jọ ìyẹn. Ẹni tí ó bá gbèrò lati ṣe aburu, lẹyin naa o wa gbe e ju silẹ, wọn maa kọ ọ fun ni dáadáa, ti ko ba wa raye ṣe e pẹlu pe ko ṣe àwọn okunfa rẹ, wọn ko nii kọ nǹkan kan, ti o ba gbe e ju silẹ ni ti ikagara, wọn maa kọ àníyàn rẹ fun un, ti o ba wa ṣe e, wọn maa kọ ọ fun un ni aburu ẹyọkan.فوائد الحديث
Ṣiṣe àlàyé ọla Ọlọhun ti o tobi lori ijọ yii nibi adipele àwọn dáadáa ati kikọ wọn ni ọdọ Rẹ, ati àìsí adipele fun aburu.
Pataki aniyan ninu awọn iṣẹ ati oripa rẹ.
Ọlá Ọlọhun ati aanu Rẹ ati dáadáa Rẹ ni pe ẹni ti o ba gbèrò dáadáa ti ko wa ṣe e, Ọlọhun maa kọ ọ ni dáadáa.