“Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ yaa maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀”

“Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ yaa maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀”

Láti ọ̀dọ̀ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- pe ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ, ki ẹ yaa maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iṣesi ti ẹrú maa n sunmọ Oluwa rẹ ju nibẹ ni ìgbà ti o ba wa ni iforikanlẹ; ìyẹn ni pe ẹni ti n kirun maa fi ibi ti o ga ju ti o si niyi ju ninu ara rẹ lé ilẹ̀ ni ti ìtẹríba ati irẹlẹ fun Ọlọhun ti O lágbára ti O gbọnngbọn, ti o si wa ni iforikanlẹ. Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti wa pàṣẹ ṣíṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ, o maa wa kójọ ninu ìyẹn irẹlẹ fun Ọlọhun pẹlu ọ̀rọ̀ ati ìṣe.

فوائد الحديث

Itẹle àṣẹ Ọlọhun maa n le ẹrú kún ni isunmọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga.

A fẹ́ ki a maa ṣe adua ni ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni iforikanlẹ; torí pé ó wa ninu awọn ààyè gbigba adua.

التصنيفات

Awọn okunfa adura gbigba ati awọn nnkan ti wọn le kọdi rẹ