“Ko si nǹkan kan ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ju adua lọ”

“Ko si nǹkan kan ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ju adua lọ”

Lati ọdọ Abu Hurairah, ki Ọlọhun yọnu si i, o gba a wa lati ọdọ Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a, o sọ pe: “Ko si nǹkan kan ti o ni apọnle ni ọdọ Ọlọhun - ti ọla Rẹ ga - ju adua lọ”

[O daa] [Tirmiziy ati Ibnu Maajah ati Ahmad ni wọ́n gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe ko si nnkan kan ninu awọn ijọsin ti o ni ọlá ni ọdọ Ọlọhun ju adua lọ; torí pé ó n bẹ ninu ẹ jijẹwọ ọ̀rọ̀ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, ati jijẹwọ ikagara ẹrú ati ìní bukaata rẹ si I.

فوائد الحديث

Ọla adua, ati pe ẹni ti o ba pe Ọlọhun ni o n gbe E tobi, ti o si n fi rinlẹ fun Un pe Ọlọ́rọ̀ ni, mimọ ni fun Un, èèyàn kii pe tálákà, Olùgbọ́ si ni, èèyàn kii pe odi, Ọlọ́rẹ ni, eeyan kii pe ahun, Aláàánú ni, èèyàn kii pe ẹni ti o le, Ọba ti O ni ikapa ni, èèyàn kii pe ẹni ti o kagara, Ọba ti O sunmọ ni, ẹni tí ó jìnnà ko lee gbọ, ati ohun ti o yatọ si ìyẹn ninu awọn ìròyìn títóbi ati ẹwà fun Ọlọhun, mimọ ni fun Un, Ọba ti ọla Rẹ ga.

التصنيفات

Ọla ti nbẹ fún adua