“Ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle, ti o wa fi janmọọn sílẹ̀, ti o wa ku, o ku ni iku ti asiko aimọkan

“Ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle, ti o wa fi janmọọn sílẹ̀, ti o wa ku, o ku ni iku ti asiko aimọkan

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i- lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pe: “Ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle, ti o wa fi janmọọn sílẹ̀, ti o wa ku, o ku ni iku ti asiko aimọkan, ẹni ti o ba ja ni abẹ àsìá kan ti o fọ́jú, ti o n binu nitori ẹlẹyamẹya, tabi o n pepe lọ sibi ẹlẹyamẹya, tabi o n ran ẹlẹyamẹya ṣe, wọn wa pa a, o jẹ pipa kan ti o jẹ ti asiko aimọkan, ẹni ti o ba jade si ijọ mi, ti o n pa ẹni rere rẹ ati ẹni buburu rẹ, ti ko bikita pipa olugbagbọ rẹ, ti ko pe adehun rẹ fun aladehun, ko si ninu ijọ mi, emi naa ko si ninu ijọ rẹ”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe dajudaju ẹni ti o ba jade kuro ninu itẹle awọn adari, ti o tu ijọ Isilaamu ti o fẹnu ko lori ṣiṣe adehun fun olori, o wa ku lori isẹsi yẹn ninu ituka ati aitẹle, o maa ku ni iku awọn asiko aimọkan, awọn ti wọn ko ki n tẹle adari ti wọn ko ki n darapọ mọ ijọ kan, bi ko ṣe pe awọn ijọ ni wọn ati awọn ẹlẹyamẹya ti awọn kan maa n ba awọn kan ja ninu wọn. . Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe ẹni ti o ba ja lábẹ́ àsìá kan ti oju ododo ko han yatọ si ibajẹ nibẹ, ti o n binu nitori ẹlẹyamẹya lasan fun ìjọ rẹ tabi idile rẹ, ti ko ki n ṣe tori riran ẹsin ati ododo ṣe, ti o wa n ja ni ti ẹlẹyamẹya laini amọdaju ati imọ, ti wọn ba pa a lori isẹsi yẹn, o da gẹgẹ bii pipa ti asiko aimọkan ni. Ati pe dajudaju ẹni ti o ba jade si ijọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti o pa ẹni rere rẹ ati ẹni buburu rẹ, ti ko bikita pẹlu nnkan ti o n ṣe ti ko si bẹru ijiya rẹ ninu pipa olugbagbọ rẹ, ti ko si pe adehun wọn fun awọn aladehun ninu awọn alaigbagbọ tabi awọn adari bi ko ṣe pe o n tu u ni, eleyii wa ninu ẹṣẹ ńláńlá, ati pe ẹni ti o ba ṣe e dajudaju o ti lẹtọọ si adehun iya ti o le koko yìí.

فوائد الحديث

Itẹle awọn adari jẹ dandan nibi nnkan ti o yatọ si ṣiṣẹ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-.

Ikilọ ti o le koko n bẹ fun ẹni ti o ba jade kuro nibi itẹle olori, ti o si tu ìjọ Musulumi ká, ti o ba ku lori isẹsi yìí, o ku lori oju ọna awọn asiko aimọkan.

Kikọ kuro nibi jija ija ẹlẹyamẹya n bẹ ninu hadiiisi náà.

Jijẹ dandan pipe adehun.

Oore topọ n bẹ ninu itẹle ati wiwa pẹlu awọn ijọ, ati ifọkanbalẹ ati ifayabalẹ, ati dida ni awọn isẹsi.

Kikọ kuro nibi fifi ara wé awọn èèyàn asiko aimọkan.

Pipaṣẹ pẹlu didunnimọ janmọọn awọn Musulumi.

التصنيفات

Jijade si imam