إعدادات العرض
“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”
“Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”
Lati ọdọ Uthman ọmọ Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ẹni ti o ba ṣe aluwala ti o si ṣe aluwala naa daadaa, awọn àṣìṣe rẹ maa jade kúrò lára rẹ titi yoo fi maa jade lati abẹ awọn èékánná rẹ”.
الترجمة
العربية Bosanski English فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Türkçe اردو 中文 हिन्दी বাংলা Español Kurdî Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili தமிழ் සිංහල မြန်မာ ไทย Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands ئۇيغۇرچە Hausa دری Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy Română Kinyarwanda नेपाली Српски Soomaali Moore Українська Български Tagalog Wolof Azərbaycanالشرح
Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ẹni ti o ba ṣe aluwala pẹlu ṣíṣe àkíyèsí awọn sunna aluwala ati awọn ẹkọ rẹ, iyẹn maa wa ninu awọn okunfa pipa awọn ẹṣẹ rẹ ati pipa àṣìṣe rẹ, titi awọn ẹṣẹ rẹ yoo fi jade labẹ awọn èékánná ọwọ rẹ mejeeji ati ti ẹsẹ rẹ méjèèjì.فوائد الحديث
Ṣisẹnilojukokoro lori ìní akolekan kikọ aluwala ati sunnah rẹ ati awọn ẹkọ rẹ, ati ṣíṣe iṣẹ pẹlu ìyẹn.
Ọla ti o n bẹ fun aluwala, ati pe o jẹ ipa ẹṣẹ keekeeke rẹ, sugbọn awọn ẹṣẹ ńlá, ironupiwada jẹ dandan lati pa wọn rẹ.
Majẹmu jijade awọn àṣìṣe ni pipe aluwala ati ṣíṣe e laisi alebu kankan gẹgẹ bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe ṣàlàyé rẹ.
Pipa ẹṣẹ rẹ ninu hadisi yii jẹ nnkan ti a de pẹlu ijina si awọn ẹṣẹ ńlá ati ironupiwada kuro nibẹ, Ọba ti ọla Rẹ ga sọ pé: (Tí ẹ bá jìnnà sí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ ńláńlá tí A kọ̀ fun yín, A máa pa àwọn ìwà àìdáa yín rẹ́ fun yín) (An-Nisa: 31).
التصنيفات
Ọla ti o n bẹ fun aluwala