إعدادات العرض
Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un
Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un
Lati ọdọ ‘Aliyy o sọ pe: Dajudaju mo jẹ ọkunrin kan ti o ṣe pe ti mo ba ti gbọ ọrọ kan lati ọdọ ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - Ọlọhun maa n fi nkan ti O ba fẹ ṣe mi ni anfaani pẹlu rẹ, ti ẹnikẹni ba wa sọrọ fun mi ninu awọn saabe rẹ (Anabi) maa ni ki o bura, ti o ba ti wa bura fun mi maa gba a gbọ, Abubakar wa sọrọ fun mi, ododo si ni Abubakar sọ, o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «Ko si ẹnìkankan ti yio da ẹṣẹ kan, lẹyin naa ni o wa dide ti o si ṣe imọra, lẹyin naa ni o wa kirun, lẹyin naa o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun ṣe aforijin fun un», lẹyin naa ni o wa ka aaya yii: {Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn} [Āl ‘Imraan: 135].
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە සිංහල हिन्दी Hausa Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or Türkçe Tiếng Việt नेपाली Malagasy Kinyarwanda తెలుగు Bosanski Lietuvių Oromoo Română മലയാളം Nederlands Soomaali Српски Kurdî Українська Deutsch ಕನ್ನಡ Wolof Mooreالشرح
Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo pe dajudaju ko si ẹru kan ti yio da ẹṣẹ kan, ti yio wa se aluwala daadaa, lẹyin naa ti yio ki irun rakaah meji pẹlu aniyan ituuba kuro nibi ẹṣẹ rẹ yii, lẹyin naa ti o wa aforijin Ọlọhun, ayaafi ki Ọlọhun fi ori jin in. Lẹyin naa ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa ka ọrọ Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ti o sọ pe: ﴾Àwọn tí (ó jẹ́ pé) nígbà tí wọ́n bá ṣe ìbàjẹ́ kan tàbí tí wọ́n bá ṣàbòsí sí ẹ̀mí ara wọn, wọ́n á rántí Allāhu, wọ́n á sì tọrọ àforíjìn fún ẹ̀ṣẹ̀ wọn, - Ta sì ni Ó ń forí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ jin (ẹ̀dá) bí kò ṣe Allāhu. Wọn kò sì takú sórí ohun tí wọ́n ṣe nígbà tí wọ́n mọ̀ (pé ẹ̀ṣẹ̀ ni).﴿ [Āl ‘Imraan: 135].فوائد الحديث
Ṣiṣe lojukokoro lori irun lẹyin naa wiwa aforijin lẹyin ẹṣẹ.
Gbigbaaye aforijin Ọlọhun ti O biyi ti O gbọnngbọn ati gbigba tituba ati iwaforijin Rẹ.
التصنيفات
Ironupiwada