إعدادات العرض
Ẹtọ ni lori gbogbo Musulumi ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje, ti yio wẹ ori rẹ ati ara rẹ
Ẹtọ ni lori gbogbo Musulumi ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje, ti yio wẹ ori rẹ ati ara rẹ
Lati ọdọ Abu Hurayra o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Ẹtọ ni lori gbogbo Musulumi ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje, ti yio wẹ ori rẹ ati ara rẹ».
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली മലയാളം Bosanski Italiano ಕನ್ನಡ Kurdî Oromoo Română Soomaali Shqip Српски Українська Wolof Tagalog Moore Malagasy தமிழ் Azərbaycan فارسی ქართული 中文 Magyarالشرح
Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – royin pe: Dajudaju iwọ ti wọn kanpa mọ lori gbogbo Musulumi ti o ti balaga ti o ni laakaye ni ki o wẹ ni ọjọ kan ninu gbogbo ọjọ meje inu ọsẹ, nitori naa yio wẹ ni ọjọ yii ori rẹ ati ara rẹ, lati fi wa imọra ati imọtoto, ati pe eyi ti o lọla ju ninu awọn ọjọ yii ni ọjọ jimọ, gẹgẹ bi wọn ṣe gbọ ọ ye ninu awọn ẹgbawa miran, ati pe wiwẹ ni ọjọ jimọ siwaju irun, nkan ti wọn fẹ (sunnah) ni ti fifẹ ti wọn kanpa mọ ni, koda ki o wẹ ni ọjọ alaamisi fun apẹrẹ, ati pe nkan ti o gbe ijẹ dandan yẹn kuro ni gbolohun ‘Aisha – ki Ọlọhun yọnu si i – pe: “Awọn eeyan jẹ oṣiṣẹ ara wọn, wọn si tun jẹ ẹni ti o ṣe pe ti wọn ba lọ fun jimọ wọn yio lọ pẹlu irisi wọn: Ni wọn wa sọ fun wọn pe: Ẹẹ ba si wa wẹ”, Bukhari lo gba a wa, ati pe ninu ẹgbawa miran fun un (Bukhari): “Wọn ni awọn oorun” iyẹn ni pe oorun oogun ati nkan ti o jọ ọ, pẹlu bẹẹ wọn sọ fun wọn pe: “Ẹẹ ba si wẹ”, nitori naa ẹni ti o yatọ si wọn lo wa ni ipo ki o ṣe e (Iwẹ) ju awọn lọ.فوائد الحديث
Akolekan Isilaamu pẹlu ìmọ́tótó ati imọra.
Iwẹ jimọ nkan ti wọn fẹ (sunnah) ni ni ti fifẹ ti wọn kanpa mọ fun irun.
Didarukọ ori bo tiẹ jẹ wipe didarukọ ara maa ko o sinu; lati le ni akolekan pẹlu rẹ ni.
Iwẹ jẹ dandan fun gbogbo ẹni ti wọn ba ri oorun ti ko daa ti awọn eeyan le maa ri inira pẹlu rẹ ni ara rẹ.
Ọjọ ti o fi n kanpa julọ fun iwẹ (sunnah) ni ọjọ jimọ; latari ọla rẹ.