Mo lọ ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe mọ fẹ gba Isilaamu, o wa pa mi láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru

Mo lọ ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe mọ fẹ gba Isilaamu, o wa pa mi láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru

Lati ọdọ Qays ọmọ ‘Aasim- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo lọ ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- pe mọ fẹ gba Isilaamu, o wa pa mi láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru.

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa]

الشرح

Qays ọmọ ‘Aasim wa ba Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o si fẹ gba Isilaamu, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ba pa a láṣẹ lati wẹ pẹlu omi ati ewe sidiru; ki o le fi ewe rẹ mọra; ati fun nnkan ti o n bẹ fun un ninu oorun dídùn.

فوائد الحديث

Ṣíṣe lofin wiwẹ alaigbagbọ nigba ti o ba fẹ wọnu Isilaamu.

Iyi ti o n bẹ fun Isilaamu ati iko akolekan rẹ pẹlu ara ati ẹmi papọ.

Iropọ omi pẹlu awọn nnkan ti wọn mọ ko mu u jade kuro nibi ijẹ mimọ rẹ.

Awọn nnkan ti o maa n mọ nnkan ti igbalode maa dipo sidiru, gẹgẹ bii ọṣẹ ati nnkan ti o jọ ọ.

التصنيفات

Awọn nnkan ti o maa n sọ iwẹ di dandan