Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”

Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”

Lati ọdọ Mahmud ọmọ Labid- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju Uthman ọmọ ‘Affan fẹ kọ mọsalasi ni awọn eniyan ba korira ìyẹn, wọn nífẹ̀ẹ́ si ki wọn fi i kalẹ bi o ṣe wa, o wa sọ pe: Mo gbọ́ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan fun Ọlọhun, Ọlọhun maa kọ iru rẹ fun un ninu alujanna”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Uthman ọmọ ‘Affan- ki Ọlọhun yọnu si i- fẹ tun mọsalasi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ ni irisi ti o daa ju kikọ akọkọ rẹ lọ, ni awọn eniyan ba korira ìyẹn; fun nnkan ti o n bẹ nibẹ ninu yiyi kikọ mọsalasi naa pada kuro nibi isẹsi kikọ rẹ ni aye Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- mọsalasi jẹ nnkan ti wọn mọ pẹlu amọ̀, ati pe òrùlé rẹ wọn mọ ọn latara imọ̀ ọ̀pẹ, ṣugbọn Uthman fẹ kọ ọ pẹlu awọn okuta ati ẹfun, Uthman- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ fun wọn nipa rẹ, ati pe oun gbọ́ ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: Ẹni ti o ba kọ mọsalasi kan lati fi wa iyọnu Rẹ- Ọba ti ọla Rẹ ga- ti ko kii ṣe ni ti karimi tabi kagbọmi, Ọlọhun A san-an lẹsan ni eyi ti o daa julọ ninu ẹsan ninu iran iṣẹ rẹ, ati pe ẹsan yii oun ni ki Ọlọhun kọ iru rẹ fun un ninu alujanna.

فوائد الحديث

Ṣisẹnilojukokoro lori kikọ awọn mọsalasi ati ọla ti o n bẹ fun ìyẹn.

Fifẹ mọsalasi ati titun un ṣe wọnu ọla ti o n bẹ fun kikọ ọ.

Pataki imọkanga fun Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- nibi gbogbo iṣẹ.

التصنيفات

Awọn idajọ awọn mọsalasi