إعدادات العرض
O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ
O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ
Lati ọdọ Tamīm ad-Dāriy - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: «O daju pe ẹsin yii a de gbogbo ibi tí oru ati ọsan de, ati pe Ọlọhun o nii fi ile kankan silẹ bóyá ilé alámọ̀ ni abi ilé onírun ayafi ki O mu ẹsin yii wọ ibẹ, pẹlu iyi abiyi tabi iyẹpẹrẹ ẹni yẹpẹrẹ, ni iyi kan ti Ọlọhun maa fi fun Isilaamu niyi ati iyẹpẹrẹ kan ti Ọlọhun maa fi yẹpẹrẹ iṣe keferi» Tamīm ad-Dāriy maa n sọ pe: Mo mọ ìyẹn ni ara awọn ara-ile mi, oore ati iyì ti ṣẹlẹ̀ fun ẹni tí o gba Isilaamu nínú wọn, ti iyẹpẹrẹ ati sísan isakọlẹ si ṣẹlẹ fun ẹni ti o jẹ keferi ninu wọn.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Türkçe اردو हिन्दी Tagalog 中文 Kurdî Português Русский دری অসমীয়া Tiếng Việt አማርኛ Svenska ไทย Кыргызча Kiswahili ગુજરાતી Hausa नेपाली Română മലയാളം Nederlands Oromoo සිංහල پښتو తెలుగు Soomaali Kinyarwanda Malagasy ಕನ್ನಡ Српски Moore ქართულიالشرح
Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ẹsin yìí maa pada kari gbogbo àwọn ipin ilẹ̀, èyíkéyìí aaye ti oru ati ọsan de ni ẹsin yìí maa pada de, Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko nii fi ile kan sílẹ̀ láéláé ni awọn ilu ati awọn oko tabi ni aṣalẹ afi ki O mu ẹsin yii wọnu rẹ, Ẹni ti o ba gba ẹsin yii ti o si ni igbagbọ ninu rẹ dajudaju o maa di abiyi pẹlu iyi Isilaamu, Ẹni ti o ba kọ ọ ti o saigbagbọ pẹlu rẹ o maa di ẹni yẹpẹrẹ ati eni ẹtẹ. Lẹyin naa, saabe ti o n jẹ Tamiim Ad-Daari- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe oun mọ ìyẹn ti ojiṣẹ Ọlọhun sọ lara awọn ara ile rẹ, torí pé ẹni ti o gba Isilaamu ninu wọn ri oore ati iyi, ẹni ti o ṣe aigbagbọ ninu wọn si ri iyẹpẹrẹ ati ẹtẹ pẹlu owo ti o tun n san fun awọn Mùsùlùmí.فوائد الحديث
Iro idunnu fun awọn Musulumi pe dajudaju ẹsin wọn maa pada fọnka si gbogbo ipin ilẹ̀.
Iyi jẹ ti Isilaamu ati awọn Musulumi ti iyẹpẹrẹ si jẹ ti aigbagbọ ati awọn alaigbagbọ.
Ẹri n bẹ nibẹ ninu awọn ẹri ìjẹ́ anabi ati ami ninu awọn ami rẹ pẹlu pe ọ̀rọ̀ náà ṣẹlẹ̀ gẹgẹ bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣe sọ.
التصنيفات
Àwọn àmì ti aye ba fẹ parẹ