Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-

Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-

Lati ọdọ ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Mo ha rakah mẹwaa lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-: Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, ati rakah meji ṣíwájú irun Subhi; o jẹ asiko kan ti wọn ko ki n wọle ti Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibẹ, Hafsoh sọ fun mi pe ti oluperun ba ti pe irun ti alufajari ba si ti yọ, o maa ki rakah meji, o wa ninu ẹgbawa kan pé: Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- maa n ki rakah meji lẹyin irun jimọh.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni i pẹ̀lú gbogbo àwọn ẹgbawa rẹ]

الشرح

Abdullahi ọmọ Umar- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- n ṣàlàyé pe: Dajudaju ninu awọn nafila ti oun ha lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jẹ rakah mẹwaa ti wọn pe wọn ni sunanur rawaatib, Rakah meji ṣíwájú irun Zuhr, ati rakah meji lẹyin rẹ, Ati rakah meji lẹyin irun Magrib ni ile rẹ, Ati rakah meji lẹyin irun Ishai ni ile rẹ, Ati rakah meji ṣíwájú irun alufajari, Ni rakah mẹwaa ba pe. Ṣugbọn irun Jimọh o maa n ki rakah meji lẹyin rẹ.

فوائد الحديث

Ṣíṣe awọn nafila yii ni nnkan ti a fẹ, ati didunni mọ wọn.

Ṣíṣe kiki naafila ninu ile lofin.

التصنيفات

Irun akigbọrẹ, Ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi irun, Ilana rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi igbeyawo ati ibasepo pẹlu awọn ara ile rẹ