إعدادات العرض
Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun
Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun
Lati ọdọ Abdullahi ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nifẹẹ si julọ? O sọ pe: "Irun kiki ni asiko rẹ", o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Lẹyin naa ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji" o sọ pe: Lẹyin naa èwo? O sọ pe: "Jija ogun si oju ọna Ọlọhun" o sọ pe: O sọ wọn fun mi, ti mo ba wa alekun rẹ dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Hausa Português Kurdî Kiswahili සිංහල Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Tiếng Việt ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or नेपाली Malagasy Kinyarwanda తెలుగు Lietuvių Oromoo Română മലയാളം Nederlands Soomaali Српски Українська Deutsch ಕನ್ನಡ Wolof Mooreالشرح
Wọn bi Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- leere pé: Ewo ninu iṣẹ ni Ọlọhun nífẹ̀ẹ́ si julọ? O sọ pe: Irun ọran-anyan kiki ni asiko rẹ ti Ọba aṣofin pa aala rẹ, Lẹyin naa, ṣíṣe daadaa si awọn obi mejeeji, pẹlu ṣíṣe daadaa si awọn mejeeji, ati mimojuto ẹtọ awọn mejeeji, ati gbigbe ṣiṣẹ awọn mejeeji ju silẹ, Lẹyin naa, jija ogun si oju ọna Ọlọhun, fun gbigbe ọrọ Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn- soke, ati dida aabo bo ẹsin Isilaamu ati awọn Musulumi, ati fifi awọn ami rẹ han, ìyẹn pẹlu ẹmi ati owo. Ọmọ Mas'ud- ki Ọlọhun yọnu si i- sọ pe: O sọ awọn iṣẹ yii fun mi; ti mo ba sọ fun un pe: Lẹyin naa èwo? Dajudaju o maa ṣe alekun rẹ fun mi.فوائد الحديث
Ini-ọla-ju-ara-wọn-lọ awọn iṣẹ laarin ara wọn wà nibamu si ifẹ Ọlọ́hun fun wọn.
Ìṣe Musulumi lojukokoro lori iko akolekan lori awọn iṣẹ ti wọn dara julọ ati eyi ti o dara tẹle e.
Iyatọ awọn ìdáhùn Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa eyi ti o dara julọ ninu awọn iṣẹ wà ni ibamu si yiyatọ awọn eniyan ati awọn isẹsi wọn, ati eyi ti o pọ julọ ni anfaani fun gbogbo ẹni kọọkan ninu wọn.