Mo ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori jijẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigbọ ati itẹle, ati ṣíṣe iṣiti fun gbogbo…

Mo ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori jijẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigbọ ati itẹle, ati ṣíṣe iṣiti fun gbogbo Musulumi

Lati ọdọ Jareer ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori jijẹrii pe ko si ẹnikan ti ijọsin tọ si afi Ọlọhun, ati pe dajudaju Muhammad ojiṣẹ Ọlọhun ni, ati gbigbe irun duro, ati yiyọ saka, ati gbigbọ ati itẹle, ati ṣíṣe iṣiti fun gbogbo Musulumi.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Saabe Jareer ọmọ Abdullahi- ki Ọlọhun yọnu si i- n sọ pe oun dunnimọ oun si ṣadehun fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori imu Ọlọhun ni ọkan ṣoṣo ati pipe awọn irun maraarun-un ti wọn jẹ ọran-anyan ni ọsan ati alẹ, pẹlu awọn majẹmu rẹ ati awọn origun rẹ ati awọn dandan rẹ ati awọn sunnah rẹ, ati lori pipe saka ti a ṣe ni ọran-anyan, oun ni ijọsin ti owo ti o jẹ dandan, ti wọn maa n gba lọwọ awọn ọlọrọ ti wọn si maa n fun awọn ti wọn lẹtọọ si i ninu awọn alaini ati awọn ti wọn yàtọ̀ si wọn, ati lori itẹle fun awọn adari, ati iṣiti fun gbogbo Musulumi, ìyẹn pẹlu ṣíṣe ojúkòkòrò láti ṣe e ni anfaani, ati mimu daadaa de ọdọ rẹ, ati titi aburu danu fun un pẹlu ọrọ ati iṣẹ.

فوائد الحديث

Pataki irun kiki ati saka yiyọ, ati pe mejeeji wa ninu awọn origun Isilaamu.

Pataki iṣiti ati ifunra ẹni ni ìmọ̀ràn laaarin awọn Musulumi, titi ti awọn saabe- ki Ọlọhun yọnu si wọn- fi ṣadehun fun ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- lori rẹ.

التصنيفات

Ọla ti o n bẹ fun irun, Ọla ti o n bẹ fun irun