Gigiṣẹ ẹru kan konii bu fún erukuru ni ojú ọna Ọlọhun ki iná wa jo

Gigiṣẹ ẹru kan konii bu fún erukuru ni ojú ọna Ọlọhun ki iná wa jo

Láti ọdọ bàbá Absin Abdur-rahman ọmọ Jabr - kí Ọlọhun yọnu si - dájúdájú òjíṣẹ Ọlọhun - kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ máa ba a - sọ pé: "Gigiṣẹ ẹru kan konii bu fún erukuru ni ojú ọna Ọlọhun ki iná wa jo".

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Òjíṣẹ Ọlọhun (kí ikẹ Ọlọhun ati ọlá Rẹ máa ba) fún wà ní ìró idunu pé ẹni tí eruku bá bó ẹsẹ rẹ mejeeji nígbàtí o njà sí oju-ọna Ọlọhun pe iná ko ní jo ẹni na.

فوائد الحديث

ìfunní ni ìró idunu fún Olujagun sí ojú ònà Ọlọhun pe yóò rí ìgbàlà ati àkóyọ ní bi Inán.

Di darukọ gigisẹ meji bó tí ẹ je pé erukuru náà yóò kárí gbógbó ará lapapọ, nitoripé ọpọlọpọ awon Olujagun nigbà náà ni won nfi ẹsẹ rìn, ti gigiṣẹ won yóò sì kó eruku ni gbógbó iṣe sí.

Ibn Hajar ṣọ pe: ti o bá ṣe pé kí eruku kan gigisẹ lasan ni yóò ṣe iná leewọ fún ni, bá wo ni tí ẹní ti o bá ṣe akitiyan ti o tun lo igbiyanju rẹ, ti o sí lo gbógbó òún tó ní nikapa.

التصنيفات

‏Ọla ti o n bẹ fun jijagun soju ọna Ọlọhun