Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ?

Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ?

Lati ọdọ Abdur Rahman ọmọ Abu Laila, o sọ pe: Ka'b ọmọ 'Ujrah pade mi, o sọ pe: Njẹ mi ko nii ta ẹ lọrẹ ọrẹ kan? Dajudaju Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- jade si wa, a sọ pé: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, a ti kọ bi a ṣe maa salamọ si ẹ, bawo ni a ṣe maa ṣe asalatu fun ẹ? o sọ pe: "Ẹ maa sọ pe: Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun, Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim, innaka Hamiidun Majeedun".

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Àwọn saabe beere lọwọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un? Lẹyin mimọ bi wọn ṣe maa salamọ fun un nibi ataya: "As salaamu alayka ayyuhan nabiyyu wa rahmatullah wa barokaatuhu...."? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ fun wọn bi wọn ṣe maa ṣe asalatu fun un, ìtumọ̀ rẹ ni pe: "Allahumo solli 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin" O túmọ̀ si pe: Ṣe ẹyin fun un pẹlu iranti ti o rẹwa ni ọdọ àwọn malaika, ati fun awọn olutẹle rẹ ninu ẹsin rẹ, ati awọn olugbagbọ ninu awọn alasunmọ rẹ. "ka maa sollaita 'alaa aali Ibrahim" Gẹgẹ bi o ṣe da ọla lori awọn ara ile Ibrahim- ki ikẹ Ọlọhun maa ba a- awọn ni Ibrahim ati Isma'il ati Ishaq ati awọn arọmọdọmọ wọn ati awọn olutẹle wọn ti wọn jẹ olugbagbọ, nitori naa, so ọla Rẹ mọ Muhammad- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-. "Innaka Hamiidun Majeedun" O n túmọ̀ si pe: Ọba ti a n gbe ẹyin fun nibi paapaa Rẹ ati awọn iroyin Rẹ ati awọn iṣẹ Rẹ, Ọba ti O gbòòrò nibi titobi Rẹ ati àṣẹ Rẹ ati ọrẹ Rẹ. "Allahumo baarik 'alaa Muhammadin wa 'alaa aali Muhammadin, ka maa baarokta 'alaa aali Ibrahim" O n túmọ̀ si pe: Fun un ninu oore ati apọn-ọnle eyi ti o tobi julọ ninu rẹ, ki o si ṣe alekun rẹ ki o si fi i rinlẹ.

فوائد الحديث

Awọn ẹni ìṣáájú wọn maa n fun ara wọn ni ẹbun àwọn ọ̀rọ̀ imọ.

Jijẹ dandan ṣiṣe asalatu fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi ataya igbẹyin nibi irun.

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fi titọrọ ikẹ ati ọla fun un mọ awọn saabe rẹ.

Ọna yii ni o pe julọ ninu awọn ọna ti o wa nibi ṣíṣe asalatu fun Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-.

التصنيفات

Awọn iranti irun, Awọn iranti irun, Awọn ẹkọ olumọ ati akẹkọ, Awọn ẹkọ olumọ ati akẹkọ