إعدادات العرض
Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
Lati ọdọ Anas- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Adura ti Anabi maa n ṣe loorekoore ju ni:(( “Ọlọ́hun, Oluwa wa, fun wa ni oore ni aye, ati rere ni ìgbẹ̀yìn, ki O si daabo bo wa nibi iya ina”.))
[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी සිංහල ئۇيغۇرچە Hausa Kurdî Português Svenska ગુજરાતી አማርኛ Tiếng Việt Kiswahili پښتو অসমীয়া دری Кыргызча or Malagasy नेपाली Čeština Oromoo Română Nederlands Soomaali മലയാളം తెలుగు ไทย Српски Kinyarwanda ಕನ್ನಡ Lietuvių Wolof தமிழ் Українська ქართული Magyar Mooreالشرح
Anabi, ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – maa n ṣe adua lọpọlọpọ pẹ̀lú àwọn adua ṣókí tí o ko nǹkan ti o pọ sinu, ninu rẹ ni: «Olúwa wa, fún wa ní oore ní ayé àti oore ní ọ̀run, kí O sì ṣọ́ wa níbi ìyà Iná» Ó ko oore ayé sínú, bíi ìpèsè arisiki ti o rọrun ti o gbooro, ti o jẹ alaali, ati ìyàwó ti o daa, ati ọmọ itutu ojú, ati ìsinmi, ati ìmọ̀ tí ó wúlò, ati iṣẹ́ rere, àti ohun tí ó jọ ìyẹn ninu awọn ohun ti èèyàn n fẹ ati ohun ti wọn ṣe ni ẹtọ, ati daadaa alukiyaamọ bii lila nibi awọn iya sàréè, ati ibuduro ni ọjọ igbende, ati iná, ati riri iyọnu Ọlọhun, ati nini idẹra gbere, ati isunmọ Oluwa Ajọkẹ-aye.فوائد الحديث
Fifẹ ṣíṣe àwọn adua ṣókí tí wọ́n ni ìtumọ̀ pupọ, lati fi kọ́ṣe Anọbi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-.
Eyi ti o fi n pé julọ ni ki ọmọnìyàn da oore ayé papọ mọ ti ọ̀run nibi adua rẹ.
التصنيفات
Awọn adura ti wọn gba wa