“Ẹni tí ó bá sọ pé: LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY'HIN KỌDIIR, ni ẹẹmẹwaa

“Ẹni tí ó bá sọ pé: LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY'HIN KỌDIIR, ni ẹẹmẹwaa

Lati ọdọ Abu Ayyuub- ki Ọlọhun yọnu si i- láti ọ̀dọ̀ Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- o sọ pé: “Ẹni tí ó bá sọ pé: LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY'HIN KỌDIIR, ni ẹẹmẹwaao da gẹgẹ bii ẹni ti o sọ ẹrú mẹrin ninu ọmọ Ismail di olómìnira”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé ẹni tí o ba sọ pe: “LAA ILAAHA ILLALLOOH WAHDAHUU LAA SHARIIKA LAHUU, LAHUL MULKU WALAHUL HAMDU, WA UWA ALAA KULLI SHAY’HIN KỌDIIR”, itumọ rẹ ni pe: Ko si ẹni ti a maa jọ́sìn fun ni ododo ayafi Ọlọhun nikan ṣoṣo tí ko ni orogun, Oun nikan si ni O ni ìjọba ti o pe, ti O si ni ẹtọ si ẹyìn pẹ̀lú ìfẹ́ ati gbigbetobi, yatọ si ẹlomiran, Olukapa si ni, nkan kan ko lee ko agara ba A. Ẹni tí ó bá pààrà asikiri nla yii ni ẹẹmẹwaa ni ojúmọ́, o maa gba irú ẹ̀san ti ẹni tí ó bá sọ ẹrú mẹ́rin di olominira ninu àwọn ọmọ Ismail ọmọ Ibrahim, ki ikẹ ati ọla maa ba àwọn méjèèjì- bá gbà, wọ́n dìídì dárúkọ àwọn ọmọ Ismail, ki ọla maa ba a; tori pe àwọn ni wọn jẹ abiyi ju àwọn mìíràn lọ.

فوائد الحديث

Ọlá ti n bẹ fun asikiri yii, eyi ti o ko ṣíṣe Ọlọhun ni Ọkan pẹ̀lú ìní ẹtọ si ìjọsìn Rẹ, ati ìjọba, ati ẹyin, ati ikapa ti o pe- sínú.

Ẹni tí ó maa ri ẹsan asikiri yii ni ẹni tí ó bá sọ ọ léraléra tabi kélekèle.

التصنيفات

Awọn ọla ti n bẹ fun iranti