Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii da lọ́fíńdà padà

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii da lọ́fíńdà padà

Láti ọ̀dọ̀ Anas ọmọ Maalik- ki Ọlọhun yọnu si i- pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii da lọ́fíńdà padà.

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Ninu ìlànà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni pe kii da lọfinda padà, o si maa n gbà á; torí pé o fúyẹ́ ni gbígbé, òórùn rẹ si dára.

فوائد الحديث

A fẹ ki a gba ẹbun lọfinda; torí pé ko si ipese kan kan fun gbígbé e, ko si si ìrègún nibi gbigba a.

Pípé ati dídára ìwà Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nibi pe kii da lọ́fíńdà pada, ati gbigba ẹ̀bùn lọ́wọ́ ẹni tí ó bá fún un.

Ṣiṣenilojukokoro lori lílo lọ́fíńdà.

التصنيفات

Awọn ẹkọ abẹwo ati igba iyonda