“Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumini maa de ipo aláàwẹ̀ ti n dide fun ìjọsìn ni oru”

“Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumini maa de ipo aláàwẹ̀ ti n dide fun ìjọsìn ni oru”

Láti ọ̀dọ̀ Aishah- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Mo gbọ ti ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe: “Dájúdájú pẹ̀lú iwa dáadáa, mumini maa de ipo aláàwẹ̀ ti n dide fun ìjọsìn ni oru”.

[O ni alaafia] [Abu Daud ni o gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ṣàlàyé pe iwa rere maa mu ẹni tí n wù ú de ipo ẹni tí n dunni mọ́ aawẹ ni ọsan ati idide fun ìjọsìn ni oru, ohun ti o ko nǹkan ti n jẹ iwa rere sinu ni: Ṣíṣe dáadáa, ati ọrọ rere, ati ìtújúká, ati ki èèyàn ma fi suta kan ẹlòmíràn, ati fifi ara da suta lati ọdọ àwọn èèyàn.

فوائد الحديث

Titobi akolekan Isilaamu si títún ìwà ṣe, ati pípé rẹ.

Ọla ti n bẹ fun iwa dáadáa, titi ti ẹrú fi maa ti ara rẹ de ipo alaawẹ ti kii tú ẹnu, ati ẹni ti n dide fun ìjọsìn ni oru ti kii rẹ̀ ẹ́.

Gbigba aawẹ ni ọsan, ati idide ni oru jẹ iṣẹ ńlá ti inira wa ninu ẹ fun ẹ̀mí, ẹni tí ó ni iwa rere de ipo àwọn méjèèjì tori jija ẹ̀mí rẹ lógun pẹ̀lú ibalopọ dáadáa.

التصنيفات

Awọn iwa ẹyin