Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ

Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ ‘Amru - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji -: Dajudaju arakunrin kan bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Isilaamu wo lo fi n loore julọ? O sọ pe: «Ki o maa funni ni ounjẹ, ki o si tun maa salamọ si ẹni ti o mọ ati ẹni ti o ko mọ».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Wọn bi Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - leere pe: Awọn iwa Isilaamu wo lo fi n lọla julọ? Ni o wa darukọ awọn iwa meji: Alakọkọọ: Pipọ ni imaa fun awọn alaini ni ounjẹ, ti saara ati ẹbun ati igbalejo ati ikolẹnujọ sì tun wọ inu rẹ, ati pe ọla ifunni l'ounjẹ tun kanpa ni awọn asiko ebi ati ọwọn gogo. Ẹlẹẹkeji ni: Sisalamọ si gbogbo musulumi, o mọ ọn ni tabi o ko tiẹ mọ ọn.

فوائد الحديث

Ṣiṣe ojukokoro awọn saabe lori mimọ awọn iwa ti yio ṣe anfaani ni aye ati ọjọ ikẹyin.

Sisalamọ ati fifunni l'ounjẹ wa ninu awọn iṣẹ ti o fi n lọla julọ ninu Isilaamu; latari ọla ti n bẹ fun un ati nini bukaata awọn eeyan si i ni gbogbo asiko.

Ṣiṣe daadaa pẹlu ọrọ ati iṣe papọ pẹlu awọn iwa mejeeji yii, ati pe oun naa si ṣiṣe daadaa ti o fi n pe julọ.

Awọn iwa yii nii ṣe pẹlu ajọṣepọ awọn Musulumi laarin ara wọn, awọn iwa kan ṣi wa ti o nii ṣe pẹlu ajọṣepọ laarin ẹru ati Olowo rẹ (Allāhu).

Imaa bẹrẹ pẹlu salamọ jẹ ẹsa laarin awọn Musulumi, nitori naa wọn o gbọdọ kọkọ salamọ si keferi.

التصنيفات

Àwọn ìwà dáadáa ati awọn ẹkọ, Awọn ẹkọ salamọ ati gbigba iyọnda