Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin

Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin

Lati ọdọ ọmọ Umar - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira ọti ni, ati pe gbogbo nkan ti o ba ti n muni hunrira eewọ ni, ati pe ẹni ti o ba mu ọti ni aye ti o wa ku ni ẹni ti o kúndùn rẹ ti ko tuuba, ko nii mu un ni ọjọ ikẹyin».

[O ni alaafia]

الشرح

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- ṣe alaye pe dajudaju gbogbo nkan ti o ba ti le mu laakaye lọ ni ọti ti n pa eeyan, yala o jẹ mímu tabi jijẹ tabi fifin simu tabi eyi ti o yato si i, ati pe dajudaju gbogbo nkan ti o le muni maa hunrira ti O si maa pa laakaye ni Ọlọhun Ọba ti O biyi ti O gbọnngbọn ti ṣe e ni eewọ ti O si tun kọ kuro nibẹ, kekere rẹ ni ati pipọ rẹ, Ati pe gbogbo ẹni ti o ba mu èyíkéyìí ninu awọn iran nkan ti o máa ń muni hunrira, ti o tun wa dunni mọ mimu un ti ko si tun tuuba ninu rẹ ti o fi ku; onítọ̀hún ti lẹtọọ si Iya Ọlọhun pẹlu ṣiṣe mimu un ni eewọ fun un ninu al-jannah.

فوائد الحديث

Okunfa ṣiṣe ọtí ni eewọ ni pipani, nitori naa gbogbo nkan ti o ba ti n pani, iran yòówù ki o jẹ, èèwọ̀ ni.

Ọlọhun ti ọla Rẹ ga ṣe ọtí ni eewọ latari nkan ti o ko sinu ni awọn inira ati awọn ibajẹ ti o tobi.

Mimu ọtí ninu al-jannah ninu pipe adun ati idẹkun ni o wa.

Ẹni ti ko ba ko ẹmi rẹ ro nibi ọti mimu ni ayé, Ọlọhun yoo ṣe mimu rẹ ni eewọ fun un ninu al-jannah, nítorí pé igba ti wọn ba fi wínkà ni wọn fi n san an.

Ṣiṣenilojukokoro lori yiyara tuuba kuro nibi ẹṣẹ ṣaaju iku.

التصنيفات

Awọn nnkan mimu ti o jẹ eewọ