{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan

{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan

Lati ọdọ Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: A jade ni alẹ ọjọ kan ti ojo n rọ ti o si ṣokunkun gidigidi, ti a n wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a; lati kirun fun wa, o sọ pe: Ni a ba ri i, ni o wa sọ pe: «Sọ», mi o si sọ nkankan, lẹyin naa o sọ pe: «Sọ», mi ò si sọ nkankan, o sọ pe: «Sọ», ni mo ba sọ pe: Kini maa sọ? O sọ pe: «{Qul Uwal Laahu ahad} ati Al-mu‘awwidhatayn (Falaqi ati Naasi) nigba ti o ba di irọlẹ ati ti o ba di afẹmọjumọ ni igba mẹta, yio to ọ nibi gbogbo nkan».

[O ni alaafia] [Abu Daud ati Tirmiziy ati Nasaa'iy ni wọn gba a wa]

الشرح

Saabe abiyi tii ṣe Abdullāh ọmọ Khubayb - ki Ọlọhun yọnu si i - n funni niroo pe: Awọn jade ni alẹ kan ti ojo pọ gan ti okunkun naa si dudu kirikiri, lati lọ wa Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a-; ki o le ki irun fun wọn, ti wọn si ri i, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: "Qul" iyẹn ni pe: ka, ko si ka nkankan, Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa tun ọrọ rẹ wi fun un, ni Abdullāh wa sọ pe: Kini ki n ka irẹ Ojiṣẹ Ọlọhun? Ni Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - wa sọ pe: Ka suuratul Ikhlaas {Qul Uwal Laahu ahad}, ati Al-Mu‘awwidhatayn {Qul a‘uudhu bi robbil falaq}, ati {Qul a‘uudhu bi robbin naas}, ni asiko irọlẹ, ati asiko aarọ, ni ẹẹmẹta yio maa sọ ọ kuro nibi gbogbo aburu, ti yio si la ọ kuro nibi gbogbo ibajẹ.

فوائد الحديث

Ṣiṣe ni sunnah kika suuratul Ikhlaas ati qul a‘uudhu mejeeji (Falaqi ati Naasi) ni aarọ ati irọlẹ ati pe isọ ni wọn jẹ kuro nibi gbogbo aburu.

Ọla ti n bẹ fun kika suuratul Ikhlaas ati Qul a‘uudhu mejeeji.

التصنيفات

Awọn iranti àárọ̀ ati irọlẹ