?Ko sí ọjọ kankan ti iṣẹ oloore inu rẹ jẹ eyi ti Ọlọhun nifẹẹ si julọ ti o to awọn ọjọ yii» ìyẹn ni awọn ọjọ mẹwaa akọkọ Dhul Hijjah

?Ko sí ọjọ kankan ti iṣẹ oloore inu rẹ jẹ eyi ti Ọlọhun nifẹẹ si julọ ti o to awọn ọjọ yii» ìyẹn ni awọn ọjọ mẹwaa akọkọ Dhul Hijjah

Lati ọdọ ọmọ Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: «Ko sí ọjọ kankan ti iṣẹ oloore inu rẹ jẹ eyi ti Ọlọhun nifẹẹ si julọ ti o to awọn ọjọ yii» ìyẹn ni awọn ọjọ mẹwaa akọkọ Dhul Hijjah, wọn sọ pe: Irẹ ojiṣẹ Ọlọhun, ati jijagun si oju ọna Ọlọhun náà? O sọ pe: «Ati jijagun si oju ọna Ọlọhun, ayaafi arakunrin kan ti o jade pẹlu ẹmi rẹ ati dukia rẹ ti ko si ṣẹri pada pẹlu nkankan ninu rẹ».

[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n ṣe alaye wipe dajudaju iṣẹ oloore ṣiṣe ninu ọjọ mẹwaa akọkọ ninu oṣu Dhul Hijjah lọla ju awọn ọjọ ọdun yooku lọ. Ni awọn saabe - ki Ọlọhun yọnu si wọn - wa beere lọwọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - nipa jijagun si oju ọna Ọlọhun ninu ọjọ ti o yatọ sí àwọn ọjọ mẹwaa yii wipe ṣe oun ni o ni ọlá julọ ni àbí awọn iṣẹ oloore ninu awọn ọjọ yii? Latari ohun ti o rinlẹ lọdọ wọn wipe jijagun si oju ọna Ọlọhun wa nínú àwọn iṣẹ ti o lọla julọ. Nigba naa ni o wa fesi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - pe: Dajudaju iṣẹ oloore ṣiṣe ninu awọn ọjọ yii lọla ju jijagun si oju ọna Ọlọhun ninu ọjọ ti o yatọ si i lọ, ayaafi arakunrin kan ti o jade ni ẹni ti n jagun ti o si n fi ẹmi rẹ ati dukia rẹ wewu ni oju ọna Ọlọhun, ti o wa padanu dukia rẹ ti ẹmi rẹ naa si tun bọ sí oju ọna Ọlọhun, Irufẹ iṣẹ yii ni yio lọla ju iṣẹ oloore ninu awọn ọjọ ọlọla yii lọ.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fun iṣẹ oloore ninu ọjọ mẹwaa Dhul Hijjah, nitori naa o jẹ dandan fun Musulumi ki o ṣe amulo awọn ọjọ yii ki o si tun pọ ni iṣẹ oloore ninu rẹ, bii riranti Ọlọhun ti O lágbára ti O si tun gbọnngbọn, ati kika Alukurāni, ati ṣiṣe gbólóhùn "Allāhu Akbar", ati gbolohun "lā ilāha illā Allāhu", ati gbolohun "AlhamduliLlāhi, ati kiki irun, ati ṣiṣe saara, ati gbigba aawẹ, ati gbogbo awọn iṣẹ oloore yòókù.

التصنيفات

‏Awọn ọjọ mẹwa inu dhul hijjah, ‏Ọla ti o n bẹ fun jijagun soju ọna Ọlọhun