Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin

Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin

Lati ọdọ Ka‘bu ọmọ ‘Ujroh - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Awọn gbolohun ẹyin irun kan n bẹ ti o ṣe pe ẹni ti o ba sọ wọn - tabi ti o ṣe wọn - ni ẹyin gbogbo irun ọranyan, ko ni mofo, subhānallāh ọgbọn ati mẹta, ati alhamduliLlāhi ọgbọn ati mẹta, ati Allāhu akbar ọgbọn ati mẹẹrin».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - funni niroo nipa awọn iranti ti ẹni ti o ba n sọ ọ o le mofo ti ko si le kabamọ, bi ko ṣe pe ẹsan awọn gbolohun yii a maa bẹ fun un, wọn o si maa wa lẹyin ara wọn, ti wọn o si tun maa sọ wọn lẹyin irun ọranyan, oun naa ni: "Subhānallāh" ọgbọn ati mẹta, iyẹn ni fifọ Ọ mọ kuro nibi adinku. Ati "AlhamduliLlāhi" ni igba ọgbọn ati mẹta, ati pe oun ni ìròyìn Ọlọhun pẹlu pipe papọ mọ ninifẹẹ Rẹ ati gbigbe titobi fun Un. Ati "Allāhu akbar" ni igba ọgbọn ati mẹẹrin, nitori pe Ọlọhun tobi O si gbọnngbọn ju gbogbo nkan lọ.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fun ṣiṣe subhānallāh ati alhamduliLlāhi ati Allāhu Akbar, ati pe awọn ni awọn iṣẹ rere to maa wa titi láéláé.

التصنيفات

Awọn iranti irun, Awọn anfaani iranti Ọlọhun- Alagbara ti O gbọnngbọn-