“Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ

“Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ

Lati ọdọ Abu Huraira- ki Ọlọhun yọnu si i-: Dajudaju ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe: “Ọjọ igbende ko lee to titi orun fi maa yọ lati ibuwọ rẹ, ti o ba ti yọ ti awọn eniyan ti wa ri i, gbogbo wọn maa gbagbọ lapapọ, ìyẹn ni igba ti: (ìgbàgbọ́ (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì gbàgbọ́ tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀ tàbí iṣẹ́ rere (tí) ẹ̀mí kan kò tí ì fi ìgbàgbọ́ rẹ̀ ṣe (tẹ́lẹ̀tẹ́lẹ̀) kò níí ṣe é ní àǹfààní (lásìkò náà)) Al-An’am, Ayah 158. Alukiyaamọ maa tó, ti ọkùnrin meji si ti tẹ aṣọ silẹ láàrin ara wọn, wọn ko si nii lee ta ọjà fun ara wọn bẹẹ ni wo ko si nii lee ka a padà, alukiyaamọ maa tó, ti èèyàn si ti bu wàrà ràkúnmí rẹ lọ ti ko si nii le mu u, alukiyaamọ maa tó, ti ó sì ti tún àmù omi rẹ ṣe, ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ mu nínú ẹ, alukiyaamọ maa tó, ti ẹnìkan nínú yin si ti gbe oúnjẹ rẹ sí ẹnu, ko si nii lee jẹ ẹ”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- n sọ pe dajudaju ninu awọn ami ọjọ igbende ti o tobi julọ ni ki oòrùn yọ lati ibuwọ rẹ dipo ki o yọ lati ibuyọ, ati pe igba ti awọn eniyan ba ri i, wọn maa gbagbọ lapapọ, Nigba yẹn igbagbọ alaigbagbọ ko nii ṣe e ni anfaani, iṣẹ rere tabi ironupiwada ko nii ṣe anfaani. Lẹyin naa Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pe dajudaju ọjọ igbende maa de lojiji; o maa tó ti awọn eniyan sì maa wa lori awọn iṣesi wọn ati lori awọn eto igbesi aye wọn; Ọjọ igbende maa de ti olutaja ati oluraja ti maa tẹ aṣọ wọn laaarin wọn ti wọn ko si nii le ta a fun ara wọn ti wọn ko si tun nii le ka a, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si ti bu wara rakunmi rẹ ti o ni wàrà tó pọ̀, ko si nii mu u, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si n tun àmù omi rẹ ṣe ti o si tun n fi amọ rẹ́ ẹ, ti ko si nii le fun awọn ẹran ọ̀sìn rẹ ni omi mu nínú ẹ, Ọjọ igbende maa de ti ọmọniyan si ti maa gbe okele rẹ de ẹnu rẹ lati jẹ ẹ ti ko si nii jẹ ẹ.

فوائد الحديث

Isilaamu ati ironupiwada maa jẹ itewọgba niwọn igba ti oorun ko ba i tii yọ lati ibuwọ rẹ.

Ṣiṣenilojukokoro lori ipalẹmọ fun ọjọ igbende pẹlu igbagbọ ati iṣẹ rere; nitori pe ọjọ igbende maa de lojiji ni.

التصنيفات

Isẹmi inu sàréè, Alaye awọn aayah