Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ

Lati ọdọ Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- o sọ pe: Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kii mọ gígé àsopọ̀ suura titi ti {BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM} fi maa sọkalẹ.

[O ni alaafia] [Abu Daud ni o gba a wa]

الشرح

Ibnu Abbaas- ki Ọlọhun yọnu si àwọn mejeeji- n ṣàlàyé pe àwọn suura Kuraani Alapọn-ọnle maa n sọ̀kalẹ̀ fun Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ko si nii mọ ibi ti asopọ rẹ ti ge ati òpin rẹ, titi ti “BISMILLAAHI RAHMAANI RAHEEM” fi maa sọ̀kalẹ̀ fun un, igba naa ni o to maa mọ pe suura ti o ṣáájú ti parí, oun si ni ibẹrẹ suura tuntun.

فوائد الحديث

A maa n fi BASMALAH ṣe opinya laarin awọn suura ni, ayafi láàrin suuratul Anfaal ati suurat At-Taobah.

التصنيفات

Sisọkalẹ Kuraani ati kiko o jọ, Kiko Kuraani jọ, Stops and Starts