Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi…

Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”

Lati ọdọ Ubay ọmọ Kahb- ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Òjíṣẹ́ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: Ọlọhun ati ojiṣẹ Rẹ ni wọn ni imọ julọ. O sọ pe: “Irẹ Abu Al-Munzir, ǹjẹ́ o mọ aaya wo ninu tira Ọlọhun ti o wa pẹlu rẹ ni o tobi julọ?”, o sọ pe: Mo sọ pé: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá} [Al-Baqarah: 255]. O sọ pe: O wa fi ọwọ́ lu mi láyà, o wa sọ pé: “Mo fi Ọlọhun búra, o kú oriire imọ naa, ki Ọlọhun ṣe e ni irọrun fun ẹ, irẹ Abu Al-Mundhir”.

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bi Ubay ọmọ Kahb léèrè nipa aaya ti o tobi ju ninu tira Ọlọhun, o wa ṣe iyèméjì nibi dáhùn, lẹ́yìn náà ni o wa sọ pé: Oun ni aayatul Kursiyy: {Allāhu, kò sí ọlọ́hun kan tí ìjọ́sìn tọ́ sí àfi Òun, Alààyè, Alámòjúútó-ẹ̀dá}, Anọbi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa ṣe atilẹyin fun un, Anọbi wa lu u ni àyà lati tọka si pe o kún fun imọ ati ọgbọ́n, o wa ṣe adua fun un pe ki o maa dunnu pẹ̀lú imọ yii ki o si rọrùn fún un.

فوائد الحديث

Ìwà rere nla ti Ubay ọmọ Kahb, ki Ọlọhun yọnu si i.

Aayatul Kursiyy ni aaya ti o tobi ju ninu tira Ọlọhun ti ọla Rẹ ga, hiha a ni ẹtọ, ati ìrònú nipa awọn ìtumọ̀ rẹ, ati lilo o.

التصنيفات

Ọla ti n bẹ fun àwọn suura ati awọn aaya, Ọla ti n bẹ fun imọ