إعدادات العرض
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun
Lati ọdọ ‘Amru ọmọ ‘Aamir lati ọdọ Anas ọmọ Mālik o sọ pe: Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun, mo wa sọ pe: Bawo ni ẹyin ṣe maa n ṣe? O sọ pe: Aluwala ẹyọkan maa n to fun ẹnikẹni ninu wa lopin igba ti ko ba ti dá ẹgbin.
[O ni alaafia] [Bukhaariy gba a wa]
الترجمة
العربية English မြန်မာ Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands اردو Bahasa Indonesia ئۇيغۇرچە বাংলা Türkçe සිංහල हिन्दी Tiếng Việt Hausa తెలుగు Kiswahili ไทย پښتو অসমীয়া دری Кыргызча Lietuvių Kinyarwanda नेपाली മലയാളം Bosanski Italiano ಕನ್ನಡ Kurdî Oromoo Română Shqip Soomaali Српски Українська Wolof Moore Tagalog Malagasy தமிழ் Azərbaycan فارسی ქართული 中文 Magyarالشرح
Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – jẹ ẹni ti maa n ṣe aluwala fun gbogbo irun ọranyan koda ki aluwala rẹ o ma bajẹ; iyẹn ni lati fi gba ẹsan ati ọla. O si tun lẹtọọ ki o ki ju irun ọranyan ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan lopin igba ti o ba ṣi ni aluwala.فوائد الحديث
Eyi ti o pọju ninu iṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – oun ni ṣiṣe aluwala fun gbogbo irun; lati fi wa eyi ti o pe julọ.
Nǹkan ti a fẹ ni ṣíṣe aluwala fun gbogbo irun.
Lilẹtọọ kiki irun ti o pọ ju ẹyọkan lọ pẹlu aluwala ẹyọkan.
التصنيفات
Ọla ti o n bẹ fun aluwala