?Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ

?Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ

Lati ọdọ Jaabir – ki Ọlọhun yọnu si i– o sọ pe: Mo gbọ ti Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – n sọ pe: «Dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati mimu orogun mọ Ọlọhun ati ṣiṣe keferi ni gbigbe irun jù silẹ».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – kilọ kuro nibi gbigbe irun ọranyan ju silẹ, o si tun sọ pe dajudaju nkan ti n bẹ laarin ọmọniyan ati kiko sinu imu orogun mọ Ọlọhun ati iṣe keferi ni gbigbe irun ju silẹ, nitori naa irun ni origun keji ninu awọn origun Isilaamu, ati pe ipo rẹ tobi ninu Isilaamu, nitori naa ẹni ti o ba gbe e ju silẹ l’ẹni ti n tako ijẹ dandan rẹ o ti di keferi pẹlu apanupọ gbogbo Musulumi, ati pe ti o ba gbe e ju silẹ patapata ni ti ifi ọwọ dẹngẹrẹ mu un ati ni ti oroju, o ti di keferi, wọn si tun gba ipanupọ awọn saabe wa lori iyẹn, ti o ba wa jẹ pe o maa n fi i silẹ ni igba miran ti yio si tun ki i ni igba miran, nigba naa o ti ni ẹtọ si adehun iya to ni agbara yii.

فوائد الحديث

Pataki irun kiki ati idunni mọ ọn, oun naa ni iyatọ laarin ṣiṣe keferi ati nini igbagbọ.

Kikọ ti o le kuro nibi gbigbe irun silẹ ati rira a lare.

التصنيفات

Awọn nnkan ti wọn maa n ba Isilaamu jẹ, Aigbagbọ, Ijẹ dandan irun ati idajọ ẹni ti o ba gbe e ju silẹ