Dajudaju iwa Anabi Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni Kuraani

Dajudaju iwa Anabi Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni Kuraani

Sa‘d ọmọ Hishām ọmọ ‘Āmir sọ – nigba ti o wọlé tọ ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i pé-: Irẹ iya awa mu’mini, fun mi ni iro nipa iwa Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – o sọ pe: Ṣe iwọ o ki n ka Alukurāni ni? Mo sọ pe: Mo maa n ka a, o sọ pe: Dajudaju iwa Anabi Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ni Kuraani.

[O ni alaafia] [Muslim ni o gba a wa nibi akojọpọ hadiisi kan ti o gun]

الشرح

Wọn bi iya awa mu’mini ‘Āisha – ki Ọlọhun yọnu si i – leere nipa iwa Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a -, o si fún wọn ní esi pẹlu gbólóhùn ṣókí kan ti o ko nkan ti o pọ sinu, o si tun ṣẹri onibeere sibi Kuraani Alapọn-ọnle eleyii ti o ko gbogbo iroyin ti o pe sinu, nígbà náà ni o wa sọ pe: O jẹ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ẹni tí maa n wuwa pẹlu awọn iwa Alukurāni. Alukurāni o nii pàṣẹ pẹlu nkankan ayaafi ki o ṣe é, ko si nii kọ kuro nibi nkankan ayaafi ki o jina si i, nitori naa iwa rẹ ni ṣiṣe iṣẹ pẹlu rẹ (Alukurāni), ati diduro nibi awọn aala rẹ, ati lilo ẹkọ pẹlu awọn ẹkọ rẹ, ati ṣiṣe ariwoye pẹlu awọn àkàwé rẹ àti awọn itan rẹ.

فوائد الحديث

Ṣiṣenilojukokoro lori ikọṣe Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – nibi iwuwasi rẹ pẹlu awọn iwa Alukurāni.

Yiyin awọn iwa ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – ati pe ninu òpó àtùpà imisi l’o ti wa.

Alukurāni ipilẹ l’o jẹ fun gbogbo awọn iwa alapọn-ọnle.

Awọn iwa ninu Isilāmu ko gbogbo ẹsin sinu pẹlu ṣiṣe awọn aṣẹ ati jijina sí awọn eewọ.

التصنيفات

‏Awọn iroyin ti iwa