Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin

Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin

Lati ọdọ Abu Hurayra – ki Ọlọhun yọnu si i– dajudaju Ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a – sọ pe: «Oluwa wa ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ṣẹku idamẹta igbẹyin, yio wa maa sọ pe: «Tani yio pe Mi ki n maa da a lohun? Tani yio bi Mi leere ki n si maa fun un? Tani yio wa aforijin Mi ki n si ṣe aforijin fun un?».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi – ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju Ọlọhun ti ọla Rẹ ga maa n sọkalẹ ni gbogbo oru si sanmọ aye nigba ti o ba ku idamẹta igbẹyin ninu oru, O si tun n ṣe awọn ẹru Rẹ ni ojukokoro ki wọn o pe E, pe Oun yio jẹ ipe ẹni ti o ba pe Oun, O si tun ṣe wọn ni oju ọyin ki wọn o bi I leere nkan ti wọn n fẹ, pe Oun yio fun ẹni ti o ba bi Oun leere, O si tun pe wọn sibi ki wọn wa aforijin Rẹ nibi awọn ẹṣẹ wọn pe Oun maa n ṣe aforijin fun awọn ẹru Oun ti wọn jẹ olugbagbọ ododo.

فوائد الحديث

Ọla ti n bẹ fun idamẹta ti o gbẹyin ni oru ati irun kiki ati adua ṣiṣe ati wiwa aforijin ninu rẹ.

O tọ fun Musulumi nigba ti o ba gbọ hadiisi yii ki o pọ ni ojúkòkòrò lori lilo awọn asiko gbigba adua.

التصنيفات

Taohiid ti àwọn orúkọ ati awọn iroyin