o kọ kuro nibi ẹjẹ jijẹ, o wa sọ pe: “Dajudaju ẹjẹ jijẹ o ki n mu oore wa, bi ko ṣe pe wọn maa n fi gba nnkan jade lati ọwọ ahun ni”

o kọ kuro nibi ẹjẹ jijẹ, o wa sọ pe: “Dajudaju ẹjẹ jijẹ o ki n mu oore wa, bi ko ṣe pe wọn maa n fi gba nnkan jade lati ọwọ ahun ni”

Lati ọdọ ọmọ Umar ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji: Lati ọdọ Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- dajudaju o kọ kuro nibi ẹjẹ jijẹ, o wa sọ pe: “Dajudaju ẹjẹ jijẹ o ki n mu oore wa, bi ko ṣe pe wọn maa n fi gba nnkan jade lati ọwọ ahun ni”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- kọ kuro nibi ileri, oun ni ki eniyan ṣe nnkan kan ni dandan fun ara rẹ ti Ọba aṣofin ko ṣe ni dandan fun un, o sọ pe: Nitori pe ileri ko ti nnkan ṣíwájú ko si lọ ọ lara, bi ko ṣe pe wọn maa n mu u jade lati ọdọ ahun ti ko ki n ṣe nnkan kan afi nnkan ti o jẹ dandan le e lori, ati pe dajudaju ileri ko ki n mu nnkan kan wa ti wọn ko tii kadara rẹ fun un.

فوائد الحديث

Wọn ko ṣe ileri ṣiṣe ni ofin, ṣùgbọ́n ti o ba ti ṣe ileri mimu u ṣẹ ti jẹ dandan fun un ti ko ba ti jẹ ẹ̀ṣẹ̀.

Idi to fa kikọ ni (oun ni pe ko ki n wa pẹlu dáadáa); nitori pe ko ki n da nnkan kan pada ninu idajọ Ọlọhun; ki oluṣe ileri ma lọ lero pe wiwaye nnkan ti o beere fun ribẹ pẹlu okunfa ileri náà, ati pe Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- rọrọ kuro nibi iyẹn.

Al-Qurtubiy sọ pe: Kikọ yii aaye rẹ ni ki o sọ ni àpẹẹrẹ pe: Ti Ọlọhun ba wo alaisan mi san saara bayii jẹ dandan le mi lori, ati pe oju pọnna kikọ ni pe nigba ti o ṣe pe ṣiṣe nnkan asunmọ ti a darukọ naa duro lori ṣiṣẹlẹ erongba ti a darukọ, o han pe aniyan asunmọ Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- ko fi ẹsẹ rinlẹ fun un, fun nnkan ti o waye lati ọwọ rẹ bi ko ṣe pe o tọ oju ọna fi kan gba ikan, o si n fi I han pe ti ko ba wo alaisan rẹ san ko nii ṣe saara pẹlu nnkan ti o so o pọ mọ lori wiwo o san, eleyii si nii iṣesi ahun, nitori pe ko nii mu nnkan kan jade ninu dukia rẹ afi pẹlu ijirọ kiakia ti yoo lekun lori nnkan ti o mu jade lọpọlọpọ igba.

التصنيفات

Awọn ìbúra ati awọn ileri