Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin

Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin

Lati ọdọ Abdur Rahmān ọmọ Abu Laylā o ni pe awọn wa ni ọdọ Hudhayfah, ni o ba beere fun omi, ni abọná kan ba fun un ni omi, nígbà tí o wa gbe ife omi yẹn fun un, o lẹ ẹ pada mọ ọn, o wa sọ pe: Ti kii ba ṣe pe mo ti kọ ọ fun un ni nkan ti kii ṣe ẹẹkan ti kii ṣe ẹẹmeji - bi ẹni ti n sọ pe: Mio ba ti ṣe nǹkan ti mo ṣe yii -, ṣugbọn mo gbọ ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - n sọ pe: Ẹ ko gbọdọ wọ aṣọ alaari, ẹ ko si gbọdọ mu ninu igba wura ati fadaka, ẹ ko si gbọdọ jẹ ninu abọ tí wọ́n fi mejeeji ṣe, nitori pe awọn (keferi) ni wọn ni i laye, tiwa (musulumi) si ni ni ọjọ ikẹyin.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi- ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a- kọ fun awọn ọkunrin kuro nibi wíwọ asọ alaari pẹlu gbogbo iran rẹ. O si kọ fun awọn obinrin ati ọkunrin kuro nibi jijẹ ati mimu ninu awọn igba ati abọ wura ati fadaka. O si sọ pe ẹsa lo jẹ fun awọn mumini ni ọjọ igbedide; nítorí pé wọn jina si i ni aye lati tẹle aṣẹ Ọlọhun, Amọ awọn keferi ko nii jẹ ti wọn ni ọjọ ikẹyin; nitori pe wọn ti kanju lo awọn nkan igbadun wọn ni ile-aye pẹlu lilo ti wọn lo o, ati ìyapa aṣẹ Ọlọhun wọn.

فوائد الحديث

Ṣiṣe wiwọ aṣọ alaari ni eewọ fun ọkunrin, ati adehun iya ti o le fun ẹni ti o ba wọ ọ.

Wọn ṣe ni ẹtọ fun awọn obinrin ki wọn wọ aṣọ alaari.

Ṣiṣe jijẹ ati mimu ninu abo wura ati fadaka ati ife wọn ni eewọ fun ọkunrin ati obinrin.

Lile Hudhayfah - ki Ọlọhun yọnu si i - nibi kikọ, o si sọ idi rẹ pe oun ti kọ fun un ni ọpọ igba kuro nibi lilo awọn igba wura ati fadaka, ṣugbọn ko jawọ.

التصنيفات

Awọn ẹkọ aṣọ wiwọ