?Mumini o gbọdọ maa korira muminah, ti o ba korira iwa kan lara rẹ, yio yọnu si omiran lara rẹ

?Mumini o gbọdọ maa korira muminah, ti o ba korira iwa kan lara rẹ, yio yọnu si omiran lara rẹ

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - o sọ pe: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ pe: «Mumini o gbọdọ maa korira muminah, ti o ba korira iwa kan lara rẹ, yio yọnu si omiran lara rẹ» tabi o sọ pe: «Yatọ si i».

[O ni alaafia] [Muslim gba a wa]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - kọ fun ọkọ ki o maa korira iyawo rẹ ni ikorira ti yio ti i debi ki o maa ṣe abosi rẹ ati ki o pa a ti ati ki o ma ya si i; nitori pe dajudaju ọmọniyan wọn da a mọ aipe ni, ti o ba wa korira iwa buruku kan ni ara rẹ, yio ri iwa miran ti o daa; nitori naa yio yọnu si èyí tí o daa ti o ṣe deede, ki o si ṣe suuru lori èyí tí ko daa ti ko yọnu si, èyí tí yio mu un ṣe suuru ti ko si nii korira rẹ ni ikorira ti yio gbe e lọ s'ibi kikọ ọ.

فوائد الحديث

Pipe mumini lọ s'ibi ṣiṣe deede ati lilo laakaye nibi èyíkéyìí ìyapa ti ba n waye pẹlu iyawo rẹ, ki o si ma maa lọ s'ibi lilo ìgbónára ati ibinu fun ìgbà díẹ̀.

Ìṣesí onigbagbọ l'ọkunrin ni ki o ma maa korira onigbagbọ l'obinrin pátápátá ni ikorira ti yio gbe e lọ s'ibi ṣiṣe opinya pẹlu rẹ, amọ èyí tí o tọ ni kí o maa ṣe amojukuro nibi nkan ti o ba korira pẹlu nkan ti o nífẹ̀ẹ́.

Ṣiṣenilojukokoro lori ibalopọ ati igbepọ daadaa laarin lọkọ laya.

Igbagbọ n pepe sibi awọn iwa rere, mumini ati muminah o si gbọdọ ma ni iwa daadaa; nitori naa igbagbọ o maa sọ bíbẹ awọn iwa ẹyin lara awọn mejeeji di dandan.

التصنيفات

Igbeyawo, Awọn idajọ awọn obinrin