إعدادات العرض
Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì…
Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a
Lati ọdọ baba Sa'eed Al-khudiriy - Ki Ọlọhun bá wa yọnu si i - Ó ní oun gbọ́ tí Òjíṣẹ Ọlọhun - Ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ̀ máa ba - tí ńsọ bayii pé: "Nígbàtí ẹnikan nínú yín bá lá àlá tí ó nifẹ sí, dajudaju ala naa lati ọdọ Ọlọhun ni ó ti wá, nitori naa ki ó fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, kó sì sọ ọ́ fún ẹniti ó bá fẹ́, ṣugbọn tí ó bá lá àlá tí ó yàtọ̀ sí eleyii, ti kò sì wuu, dajudaju lati ọdọ èṣù ni o ti wá, ki iru ẹni bẹẹ yaa bẹ Ọlọhun fún ààbò àti iṣọ nibi aburu àlá naa, bẹẹ ni ki ó má rọ́ àlá náà fún ẹnikankan, ti kò bati rọ ọ fún ẹnikankan àlá náà kò ní kó ìnira ba a".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Bahasa Indonesia Türkçe اردو 中文 हिन्दी Tagalog Français ئۇيغۇرچە Hausa Kurdî Kiswahili Português සිංහල Русский Nederlands Tiếng Việt ગુજરાતી অসমীয়া አማርኛ پښتو ไทย नेपाली മലയാളം Oromooالشرح
Anọbi - ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa bá a - fún wa ní ìró pé dajudaju àlá daada tí ó ń múnú ẹni dùn lójú orun wá lati ọdọ Ọlọhun, Anọbi sì tọ wa sọna pe kí a fi ọpẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ẹni naa sì lè sọ jade, ṣugbọn ti ó bá lálàá rí nkan tí kò fẹ́, tabi nkan tó ba a nínú jẹ́, lati ọdọ eṣu ni ó tiwa, ki o yáa wá iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, kí ó má ṣe rọ́ àlá náà tabi sọfún ẹnikankan, dájúdájú kò nii kó ìnira bá a nígbàtí o jẹ wipe Ọlọhun ti fi nkan táa sọ yii ṣe okunfa ọlà ati akoyọ kuro nibi nkan ti a kò fẹ, eyi ti ó lè fẹ ṣẹlẹ latara àlá náà.فوائد الحديث
Awọn ipin àlá:
1. Àlá tí ó dáa, ohun ni àlá òtitọ ati ifunni ní iro idunu lati ọdọ Ọlọhun, eniyan lè la a funra rẹ tabi ki wọ́n la a si i. 2. Ọ̀rọ̀ tẹmi banusọ, ohun ni ọrọ ti ènìyàn ba ara rẹ sọ ní feteete (ni oju aiye)
3. Ibani nínú jẹ ati iṣẹru bani lati ọdọ èṣù (satani), ati ikoni laya jẹ lati ọdọ rẹ; lati fí kó ìbànújẹ́ bá eniyan.
Kókó nkan ti wọ́n sọ nípa àlá dáada mẹta ni: Kí o dupẹ fún Allah (Ọlọhun) lori rẹ, ki o dunnu nipa rẹ, kí o sí sọ ọ fun àwọn eniyan, ṣugbọn awọn tí o nifẹ nikan nio laiṣe awọn ti o korira.
Àpapọ̀ nkan ti wọ́n sọ nípa àlá buruku tí kò daa marun ni: ki a bere iṣọra lọdọ Ọlọhun kuro nibi aburu rẹ, ati nibi aburu èṣù, ki a sì fẹ atẹgun ẹnu wa sí apá òsì wa lẹẹmẹta nigba ti a bá jí, bẹẹ a kò gbọdọ bá ẹnikankan sọrọ nipa rẹ, ti ènìyàn náà bá fẹ sùn pada, kí ó yí ẹgbẹ ti o fi sun pada, àlá buruku naa kò nii kó ìnira ba a.
Ibn Hajar sọ pe: Òye tabi idi pataki tí ó wà nibẹ ni pe tí ó bá rọ́ àlá dáada fún ẹnití kò nifẹ rẹ, irufẹ ẹni bẹẹ lè tumọ àlá náà fún-un sí nkan tí kò fẹ́, yálà nítorí pé o n binu si daada ti o rí, tabi ni ti keeta ati ẹ̀gàn, o ṣeeṣe kí àlá náà ṣẹlẹ gẹgẹ bí wọn ṣe tumọ rẹ, tabi ki ẹni ti ó lálàá máa kánjú fúnrara rẹ fún ìbànújẹ ati aidunnu ọkan, nítorí rẹ ni wọn fi paá laṣẹ pe kí ó má ṣe sọ àlá náà fún ẹniti kò nifẹ sii.
Kí a máa dúpẹ́ fún Ọlọhun nigbati awọn idẹra bá n dé sinu aiye wa, ti awọn aanu sì nwá lọtun lọtun; eleyii ni òkùnfà tí idẹra náà máa fi pẹ́.
التصنيفات
Awọn ẹkọ ala