إعدادات العرض
Iwọ yoo lọ sí ọdọ awọn eniyan kan ti wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀, tí o bá dé ọdọ wọn, pẹ̀ wọn kí o sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe
Iwọ yoo lọ sí ọdọ awọn eniyan kan ti wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀, tí o bá dé ọdọ wọn, pẹ̀ wọn kí o sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe
Lati ọdọ ọmọ Abbas - ki Ọlọhun yọnu si awọn mejeeji - ó sọ pé: Ojiṣẹ Ọlọhun - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - sọ fun Muaz ọmọ Jabal, nigba ti ó ran an lọ sí ilu Yemen pé: "Iwọ yoo lọ sí ọdọ awọn eniyan kan ti wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀, tí o bá dé ọdọ wọn, pẹ̀ wọn kí o sọ fún wọn pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju ko si ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe, tí wọ́n bá gba ẹ gbọ́ nínú ìyẹn, sọ fún wọn pé dajudaju Ọlọhun ti ṣe irun wakati márùn-ún ní ọranyan lé wọn lori ni ojoojumọ, tí wọ́n bá gba e gbọ́ nínú ìyẹn, sọ fún wọn pé Ọlọ́hun ti ṣe zakat ní ọranyan lé wọn lori, kí wọ́n maa gbà a lọ́wọ́ àwọn olówó inu wọn, kí wọ́n sì maa fún awọn talaka inu wọn, tí wọ́n bá gba ẹ gbọ́ nínú ìyẹn, ó wá dọwọ́ ẹ o nibi awọn nkan tó niye lori ninu awọn dukia wọn, kí o sì bẹ̀rù ipepe eni tí a ṣe àbòsí sí, nítorí pé kò sí gaga kankan láàrín rẹ̀ àti Ọlọ́hun".
الترجمة
العربية বাংলা Bosanski English Español فارسی Français Bahasa Indonesia Русский Tagalog Türkçe اردو 中文 हिन्दी ئۇيغۇرچە Kurdî Hausa Português മലയാളം తెలుగు Kiswahili မြန်မာ Deutsch 日本語 پښتو Tiếng Việt অসমীয়া Shqip Svenska Čeština ગુજરાતી አማርኛ Nederlands සිංහල தமிழ் ไทย دری Akan Български Fulfulde Magyar Italiano ಕನ್ನಡ Кыргызча Lietuvių Malagasy नेपाली or Română Kinyarwanda тоҷикӣ O‘zbek Azərbaycan Moore Wolof Oromoo Soomaali Українська bm km rn ქართული Македонски Српскиالشرح
Nigba ti Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - rán muaz ọmọ Jabal - ki Ọlọhun yọnu si i - lọ sí ilu Yemen lati lọ kéde ẹ̀sìn Ọlọhun fún wọn, kí ó sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ẹ̀sìn Islam, ó ṣalaye fun un pé dajudaju ó máa ṣalabapade awọn ọmọ Kristẹni kan nibẹ; nitori naa, ki o gbaradi fun wọn, lẹyin naa, ki o bẹrẹ ikede ẹsin Islam fun wọn pẹlu sísọ nkan tó pataki julọ, lẹyin naa ki o wá sọ nkan tó pataki tèlé e, Kí ó kọ́kọ́ pè wọ́n lọ síbi ṣiṣatunṣe igbagbọ wọn; iyẹn ni pé kí wọ́n jẹrii pé dajudaju kò sí ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah, ati pé dajudaju Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní n ṣe; Nítorí pé eyi ni ó máa mú wọn wọ inu ẹsin Islam, tí wọ́n bá ti gbà lati ṣe iyẹn, kí ó ṣẹ̀ṣẹ̀ waa pa wọ́n laṣẹ pé kí wọ́n maa gbé ìrun duro; nitori pe irun ni iṣẹ ọranyan tí ó tóbi jùlọ lẹyin tí a bá ti ṣe Ọlọhun lọ́kan, tí wọ́n bá gbé irun naa duro, kí o pa àwọn olówó inu wọn láṣẹ pé kí wọ́n yọ zakat owó wọn fún àwọn tálákà inu wọn, lẹ́yìn náà, Anabi ṣe ìkìlọ̀ fún Muaz pé kó má ṣe gba owó tó níye lórí jù lọ; nitori pe eyi tó jẹ́ ọranyan ni eyi tó wà ní iwọntun-wọnsì lẹyin naa, ó tún gbà á nímọ̀ràn pé kó jìnà sí àbòsí; nitori ki ẹni tí ó bá ṣabosi sí má baa ṣepe fun un, nitori pé dajudaju adura rẹ̀ maa gbà.فوائد الحديث
Itumọ ijẹrii pé kò sí ọlọhun miran ayafi Ọlọhun Allah ni pé ki a ṣe Ọlọhun lọ́kan ṣoṣo nibi ijọsin wa, kí a sì gbé ijọsin ohun tó yatọ si I jù sílẹ̀.
Itumọ ijẹrii pé Anabi Muhammad Ojiṣẹ Ọlọhun ní ń ṣe ni pé kí a ní igbagbọ si i, kí a sì ní igbagbọ sí ohun tí ó mú wá, kí a sì pè é lódodo, ati pé oun ni ikẹhin awọn Ojiṣẹ Ọlọhun sí gbogbo ènìyàn.
Bí a ṣe maa bá oní mímọ̀ sọ̀rọ̀ ati ẹniti ó ní ìrújú, ó yatọ si bi a ṣe maa bá alaimọkan sọrọ; nítorí náà ni Anabi ṣe ṣalaye fún Muaz pé: “Ìwọ yóò lọ bá àwọn ènìyàn tí wọ́n jẹ́ oni-tira sánmọ̀”.
Pàtàkì kí musulumi jẹ́ onimimọ nipa ẹsin rẹ̀; kí ó lè móríbọ́ kuro nibi ìrújú awọn onírújú, látara wíwá ìmọ̀.
Bíbàjẹ́ ẹsin awọn Yahudi ati Nasara lẹyin tí Ọlọhun ti gbé Anabi Muhammad dìde - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ati pé wọn kò sí ninu awọn ti yoo là ní ọjọ igbende ayafi tí wọ́n bá wọ inu ẹsin Islam, kí wọ́n sì gba Anabi gbọ - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a.
التصنيفات
Ẹsin Isilaamu