?Ọlọhun o nii gba irun ẹnikẹni ninu yin ti o ba ti ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe aluwala

?Ọlọhun o nii gba irun ẹnikẹni ninu yin ti o ba ti ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe aluwala

Lati ọdọ Abu Hurayra - ki Ọlọhun yọnu si i - lati ọdọ Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - o sọ pe: «Ọlọhun o nii gba irun ẹnikẹni ninu yin ti o ba ti ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe aluwala».

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Anabi - ki ikẹ ati ọla Ọlọhun maa ba a - ṣe alaye pe dajudaju ninu awọn majẹmu nini alafia irun ni: Imọra, nitori naa o jẹ dandan fun ẹni ti o ba fẹ ki irun ki o ṣe aluwala ti o ba ṣe pe ọkan ninu awọn nkan ti o maa n ba aluwala jẹ ba ṣẹlẹ si i; gẹgẹ bii igbẹ tabi itọ tabi oorun tabi nkan ti o yatọ si i.

فوائد الحديث

Wọn o nii gba irun ẹni ti o ni ẹgbin lara titi ti yio fi ṣe imọra pẹlu iwẹ kuro nibi ẹgbin nla ati pẹlu aluwala kuro nibi ẹgbin kekere.

Aluwala oun ni bibu omi ati yiyi i po ninu ẹnu ati titu u jade, lẹyin naa ni fifi eemi rẹ fa omi si inu imu, lẹyin naa ni fifin in jade, lẹyin naa ni fifọ oju ni ẹẹmẹta, lẹyin naa ni fifọ ọwọ mejeeji de igunpa ni ẹẹmẹta, lẹyin naa ni pipa gbogbo ori ni ẹẹkan, lẹyin naa ni fifọ ẹsẹ mejeeji de koko ẹsẹ ni ẹẹmẹta.

التصنيفات

Aluwala, Aluwala