”O ti jere ti o ba sọ ododo”

”O ti jere ti o ba sọ ododo”

Lati ọdọ Tolha ọmọ 'Ubaidullah - ki Ọlọhun yọnu si i- o sọ pe: Arákùnrin kan wa ba ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ninu awọn ara Najd, ti irun ori rẹ ri wúruwùru ti ohun rẹ n lọ sókè ti a o si gbọ́ ohun ti n sọ yé, titi ti o fi sunmọ ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ni o ba n beere nipa Isilaamu, ni ojiṣẹ Ọlọhun – ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a – wa sọ pé: “Irun wákàtí márùn-ún ni ojúmọ́”, o wa sọ pe: Ǹjẹ́ nǹkan míì tun jẹ dandan le mi lórí yàtọ̀ si i? O sọ pe: “Rara, àfi ti o ba fẹ ṣe aṣegbọrẹ, ati aawẹ oṣù Ramadan”, o sọ pe: Ǹjẹ́ nǹkan mii tún jẹ́ dandan fún mi yàtọ̀ sí i? O sọ pe: “Rara, afi ti o ba fẹ ṣe aṣegbọrẹ”, ojiṣẹ Ọlọhun- kí ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- wa dárúkọ sàká fun un, o sọ pe: Njẹ omiran lẹyin wọn jẹ dandan fun mi? O sọ pe: “Rara, afi ki o ṣe aṣegbọrẹ”, o sọ pe: Ni arakunrin naa yi ẹsẹ pada, o wa n sọ pe: Mo fi Ọlọhun bura, mi ko nii lekun lori eyi, mi ko nii dinkun ninu rẹ, ni ojiṣẹ Ọlọhun- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: ”O ti jere ti o ba sọ ododo”.

[O ni alaafia] [Ohun ti wọ́n fi ẹnu kò lé lórí ni]

الشرح

Arakunrin kan ninu awọn ara Najd wa sọ́dọ̀ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- ti irun rẹ ri wuruwuru, ti ohun rẹ lọ sókè, ti wọn ko gbọ nnkan ti o n sọ ye, titi o fi sunmọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a-, ti o si beere nipa awọn ọran-anyan Isilaamu? Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bẹ̀rẹ̀ pẹlu irun, ti o si sọ fun un pe dajudaju Ọlọhun ṣe irun marun-un ni ọran-anyan le e lori ni gbogbo ọ̀sán ati oru. O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn irun yàtọ̀ si awọn marun-un yii? O sọ pe: Rara, afi ti o ba ki nafila lati ṣe aṣegbọrẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ pé: Ninu nnkan ti Ọlọhun tun ṣe e ni dandan le ẹ lori ni awẹ oṣu Ramadan. O sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awẹ yàtọ̀ si awẹ Ramadan? O sọ pe: Rara, afi ti o ba gba aawẹ fun aṣegbọrẹ. Lẹyin naa, Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- dárúkọ saka fun un. Arakunrin naa sọ pe: Njẹ nnkan kan tun jẹ dandan fun mi ninu awọn saara lẹyin saka ọran-anyan? O sọ pe: Rara, a fi ti o ba ṣe aṣegbọrẹ. Lẹyin igba ti arakunrin naa gbọ́ lati ọdọ Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- nipa awọn ọran-anyan yìí, o pẹyin da, o si búra pẹlu Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pe oun maa dunni mọ́ ọn laisi alekun tabi adinku, ni Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- sọ lẹyin ìyẹn pé: Ti arakunrin naa ba sọ ododo lori nnkan ti o bura le lori dajudaju o maa wa ninu awọn olujere.

فوائد الحديث

Rirọ Sharia ti Isilaamu ati ṣíṣe irọrun rẹ fun awọn ti a la iwọ̀ Ọlọhun bọ lọrun.

Didara ibalopọ rẹ- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- fun arakunrin yìí, o ṣe e ni irọrun fun un lati sunmọ ọn ati lati béèrè lọwọ rẹ.

Bibẹrẹ ipepe soju ọna Ọlọhun- ti ọla Rẹ ga- pẹlu eyi ti o pataki julọ lẹ́yìn náà ni o wa n kan eyi ti o ba tun pàtàkì tẹle e.

Isilaamu jẹ adisọkan ati iṣẹ, iṣẹ kan ko lee ṣe anfaani laisi igbagbọ, igbagbọ kan o si lee ṣe anfaani laisi iṣẹ.

Pataki awọn iṣẹ yii, ati pe wọn wa ninu origun Isilaamu.

Irun jimọh ti wọnu awọn irun maraarun-un ti wọn jẹ dandan; nitori pe o jẹ ijirọ fun irun Zuhr ni ọjọ jimọh fun ẹni ti o ba jẹ dandan fun.

Anabi- ki ikẹ Ọlọhun ati ọla Rẹ maa ba a- bẹ̀rẹ̀ lati kọ́ ọ ni ẹkọ pẹlu eyi ti o kanpa julọ ninu awọn ọran-anyan Isilaamu, oun ni awọn origun rẹ lẹyin ijẹrii mejeeji; nitori pe o jẹ Musulumi, ko dárúkọ hajj; nirori pe ko i tii di ọranyan ni igba naa, tabi ki àsìkò rẹ o ma i tii to.

Ọmọniyan ti o duro lori nnkan ti o jẹ dandan nikan ninu ofin dajudaju o ti jẹ olujere, ṣùgbọ́n eyi ko túmọ̀ si pe wọn ko ṣe ni sunnah fun un lati mu aṣegbọrẹ wá; nitori pe aṣegbọrẹ, ọran-anyan maa n pe tan pẹlu rẹ ni ọjọ igbedide.

التصنيفات

Ẹsin Isilaamu